Surah An-Nisa Verse 18 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَلَيۡسَتِ ٱلتَّوۡبَةُ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ حَتَّىٰٓ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ ٱلۡمَوۡتُ قَالَ إِنِّي تُبۡتُ ٱلۡـَٰٔنَ وَلَا ٱلَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمۡ كُفَّارٌۚ أُوْلَـٰٓئِكَ أَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا
Kò sí ìronúpìwàdà fún àwọn t’ó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísinsìn yìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn t’ó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n