Surah An-Nisa Verse 36 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisa۞وَٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡـٔٗاۖ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنٗا وَبِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡجَارِ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡجَارِ ٱلۡجُنُبِ وَٱلصَّاحِبِ بِٱلۡجَنۢبِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ مَن كَانَ مُخۡتَالٗا فَخُورًا
E josin fun Allahu, e ma se fi nnkan kan sebo si I. E se daadaa si awon obi mejeeji ati ebi ati awon omo orukan ati awon mekunnu ati aladuugbo t’o sunmo ati aladuugbo t’o jinna ati ore alabaarin ati eni ti agara da lori irin-ajo ati awon eru yin. Dajudaju Allahu ko nifee onigbeeraga, afonnu