Surah An-Nisa Verse 43 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡرَبُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنتُمۡ سُكَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَعۡلَمُواْ مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِي سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغۡتَسِلُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوًّا غَفُورًا
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ọ̀kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ t’ó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn