Surah An-Nisa Verse 46 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaمِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِۦ وَيَقُولُونَ سَمِعۡنَا وَعَصَيۡنَا وَٱسۡمَعۡ غَيۡرَ مُسۡمَعٖ وَرَٰعِنَا لَيَّۢا بِأَلۡسِنَتِهِمۡ وَطَعۡنٗا فِي ٱلدِّينِۚ وَلَوۡ أَنَّهُمۡ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَأَطَعۡنَا وَٱسۡمَعۡ وَٱنظُرۡنَا لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ وَأَقۡوَمَ وَلَٰكِن لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُونَ إِلَّا قَلِيلٗا
Ó ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn t’ó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́, a ò gba tìrẹ. Òmùgọ̀ wa.” Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn)