Surah An-Nisa Verse 58 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisa۞إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُكُمۡ أَن تُؤَدُّواْ ٱلۡأَمَٰنَٰتِ إِلَىٰٓ أَهۡلِهَا وَإِذَا حَكَمۡتُم بَيۡنَ ٱلنَّاسِ أَن تَحۡكُمُواْ بِٱلۡعَدۡلِۚ إِنَّ ٱللَّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُم بِهِۦٓۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ سَمِيعَۢا بَصِيرٗا
Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn. Àti pé nígbà tí ẹ bá ń dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, ẹ dájọ́ pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu ń fi n̄ǹkan t’ó dára ṣe wáàsí fun yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran