Surah An-Nisa Verse 78 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaأَيۡنَمَا تَكُونُواْ يُدۡرِككُّمُ ٱلۡمَوۡتُ وَلَوۡ كُنتُمۡ فِي بُرُوجٖ مُّشَيَّدَةٖۗ وَإِن تُصِبۡهُمۡ حَسَنَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِكَۚ قُلۡ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ فَمَالِ هَـٰٓؤُلَآءِ ٱلۡقَوۡمِ لَا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ حَدِيثٗا
Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí l’ó ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan