Surah Al-Maeda Verse 12 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maeda۞وَلَقَدۡ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ وَبَعَثۡنَا مِنۡهُمُ ٱثۡنَيۡ عَشَرَ نَقِيبٗاۖ وَقَالَ ٱللَّهُ إِنِّي مَعَكُمۡۖ لَئِنۡ أَقَمۡتُمُ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَيۡتُمُ ٱلزَّكَوٰةَ وَءَامَنتُم بِرُسُلِي وَعَزَّرۡتُمُوهُمۡ وَأَقۡرَضۡتُمُ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا لَّأُكَفِّرَنَّ عَنكُمۡ سَيِّـَٔاتِكُمۡ وَلَأُدۡخِلَنَّكُمۡ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ فَمَن كَفَرَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ مِنكُمۡ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ
Dajudaju Allahu gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si gbe ijoye mejila dide ninu won. Allahu si so fun won pe: “Dajudaju Mo n be pelu yin, ti e ba n kirun, ti e ba n yo Zakah, ti e ba n gba awon Ojise Mi gbo, ti e ba n ran won lowo, ti e ba n ya Allahu ni dukia t’o dara. Dajudaju Mo maa pa awon asise yin re. Dajudaju Mo maa mu yin wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Amo enikeni ti o ba sai gbagbo leyin iyen ninu yin, o ti sina kuro loju ona.”