Surah Al-Maeda Verse 14 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaوَمِنَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّا نَصَٰرَىٰٓ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَهُمۡ فَنَسُواْ حَظّٗا مِّمَّا ذُكِّرُواْ بِهِۦ فَأَغۡرَيۡنَا بَيۡنَهُمُ ٱلۡعَدَاوَةَ وَٱلۡبَغۡضَآءَ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَسَوۡفَ يُنَبِّئُهُمُ ٱللَّهُ بِمَا كَانُواْ يَصۡنَعُونَ
Àti pé lọ́dọ̀ àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú nasara ni àwa.”, A gba àdéhùn lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A fi ṣe ìrántí fún wọn. Nítorí náà, A gbin ọ̀tá àti ọ̀tẹ̀ sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Láìpẹ́ Allāhu máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́