Surah Al-Maeda Verse 2 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُحِلُّواْ شَعَـٰٓئِرَ ٱللَّهِ وَلَا ٱلشَّهۡرَ ٱلۡحَرَامَ وَلَا ٱلۡهَدۡيَ وَلَا ٱلۡقَلَـٰٓئِدَ وَلَآ ءَآمِّينَ ٱلۡبَيۡتَ ٱلۡحَرَامَ يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّهِمۡ وَرِضۡوَٰنٗاۚ وَإِذَا حَلَلۡتُمۡ فَٱصۡطَادُواْۚ وَلَا يَجۡرِمَنَّكُمۡ شَنَـَٔانُ قَوۡمٍ أَن صَدُّوكُمۡ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ أَن تَعۡتَدُواْۘ وَتَعَاوَنُواْ عَلَى ٱلۡبِرِّ وَٱلتَّقۡوَىٰۖ وَلَا تَعَاوَنُواْ عَلَى ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se ru ofin awon nnkan arisami ti Allahu gbe kale fun esin Re. E ma se so osu owo di eto (fun ogun esin), E ma se idiwo fun awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. E ma se idiwo fun awon t’o n gbero lati lo si Ile Haram, ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Oluwa won. Ti e ba si ti tura sile ninu aso hurumi, nigba naa e (le) dode (eranko). E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati tayo enu-ala nitori pe won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram. E ran ara yin lowo lori ise rere ati iberu Allahu. E ma se ran ara yin lowo lori (iwa) ese ati itayo enu-ala. E beru Allahu. Dajudaju Allahu le (nibi) iya