Surah Al-Maeda Verse 33 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaإِنَّمَا جَزَـٰٓؤُاْ ٱلَّذِينَ يُحَارِبُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَسۡعَوۡنَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَسَادًا أَن يُقَتَّلُوٓاْ أَوۡ يُصَلَّبُوٓاْ أَوۡ تُقَطَّعَ أَيۡدِيهِمۡ وَأَرۡجُلُهُم مِّنۡ خِلَٰفٍ أَوۡ يُنفَوۡاْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِۚ ذَٰلِكَ لَهُمۡ خِزۡيٞ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Ẹ̀san àwọn t’ó ń gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ni pé, kí ẹ pa wọ́n tàbí kí ẹ kàn wọ́n mọ́ igi àgbélébùú tàbí kí ẹ gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn ní ìpasípayọ tàbí kí ẹ lé wọn kúrò nínú ìlú. Ìyẹn ni ìyẹpẹrẹ fún wọn nílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run