Surah Al-Maeda Verse 4 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaيَسۡـَٔلُونَكَ مَاذَآ أُحِلَّ لَهُمۡۖ قُلۡ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُ وَمَا عَلَّمۡتُم مِّنَ ٱلۡجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ ٱللَّهُۖ فَكُلُواْ مِمَّآ أَمۡسَكۡنَ عَلَيۡكُمۡ وَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهِۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: "Kí ni Wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?" Sọ pé: “Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fun yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i . Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́