Surah Al-Maeda Verse 48 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaوَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَمُهَيۡمِنًا عَلَيۡهِۖ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡ عَمَّا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡحَقِّۚ لِكُلّٖ جَعَلۡنَا مِنكُمۡ شِرۡعَةٗ وَمِنۡهَاجٗاۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن لِّيَبۡلُوَكُمۡ فِي مَآ ءَاتَىٰكُمۡۖ فَٱسۡتَبِقُواْ ٱلۡخَيۡرَٰتِۚ إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
A so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. O n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ninu Tira. O n wa aabo fun awon ofin inu re. Nitori naa, fi ohun ti Allahu sokale dajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won t’o yapa si ohun ti o de ba o ninu ododo. Olukuluku ninu yin ni A ti se ofin ati ilana fun. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin ni. Nitori naa, e gbawaju nibi ise rere. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. O si maa fun yin ni iro nipa ohun ti e n yapa enu si