Surah Al-Maeda Verse 49 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaوَأَنِ ٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡ وَٱحۡذَرۡهُمۡ أَن يَفۡتِنُوكَ عَنۢ بَعۡضِ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ إِلَيۡكَۖ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَٱعۡلَمۡ أَنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُصِيبَهُم بِبَعۡضِ ذُنُوبِهِمۡۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ لَفَٰسِقُونَ
Àti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́