Surah Al-Maeda Verse 6 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قُمۡتُمۡ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ فَٱغۡسِلُواْ وُجُوهَكُمۡ وَأَيۡدِيَكُمۡ إِلَى ٱلۡمَرَافِقِ وَٱمۡسَحُواْ بِرُءُوسِكُمۡ وَأَرۡجُلَكُمۡ إِلَى ٱلۡكَعۡبَيۡنِۚ وَإِن كُنتُمۡ جُنُبٗا فَٱطَّهَّرُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُم مِّنۡهُۚ مَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيَجۡعَلَ عَلَيۡكُم مِّنۡ حَرَجٖ وَلَٰكِن يُرِيدُ لِيُطَهِّرَكُمۡ وَلِيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ̀ ń bẹ lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́