Surah Al-Maeda Verse 68 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaقُلۡ يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَسۡتُمۡ عَلَىٰ شَيۡءٍ حَتَّىٰ تُقِيمُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُمۡۗ وَلَيَزِيدَنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم مَّآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗاۖ فَلَا تَأۡسَ عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́