Surah Al-Maeda Verse 95 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡتُلُواْ ٱلصَّيۡدَ وَأَنتُمۡ حُرُمٞۚ وَمَن قَتَلَهُۥ مِنكُم مُّتَعَمِّدٗا فَجَزَآءٞ مِّثۡلُ مَا قَتَلَ مِنَ ٱلنَّعَمِ يَحۡكُمُ بِهِۦ ذَوَا عَدۡلٖ مِّنكُمۡ هَدۡيَۢا بَٰلِغَ ٱلۡكَعۡبَةِ أَوۡ كَفَّـٰرَةٞ طَعَامُ مَسَٰكِينَ أَوۡ عَدۡلُ ذَٰلِكَ صِيَامٗا لِّيَذُوقَ وَبَالَ أَمۡرِهِۦۗ عَفَا ٱللَّهُ عَمَّا سَلَفَۚ وَمَنۡ عَادَ فَيَنتَقِمُ ٱللَّهُ مِنۡهُۚ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se pa eran-igbe nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Enikeni ti o ba si moomo pa a ninu yin, itanran re ni (pe o maa pa) iru ohun ti o pa ninu eran osin. Awon onideede meji ninu yin l’o si maa se idajo (osuwon) re (fun un. O je) eran itanran ti o maa mu de Kaaba. Tabi ki o fi bibo awon talika se itanran. Tabi aaro iyen ni aawe, nitori ki o le to bi oran re se lagbara to wo. Allahu ti moju kuro nibi ohun t’o re koja. Enikeni ti o ba tun pada (moomo dode ninu aso hurumi), Allahu yoo gbesan lara re re. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan