Surah Al-Anaam Verse 100 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَجَعَلُواْ لِلَّهِ شُرَكَآءَ ٱلۡجِنَّ وَخَلَقَهُمۡۖ وَخَرَقُواْ لَهُۥ بَنِينَ وَبَنَٰتِۭ بِغَيۡرِ عِلۡمٖۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يَصِفُونَ
Wọ́n sì fi àwọn àlùjànnú ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dàá wọn! Wọ́n tún parọ́ mọ́ Ọn (pé) Ó bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, láì nímọ̀ kan (nípa Rẹ̀). Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)