Surah Al-Anaam Verse 108 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَلَا تَسُبُّواْ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ فَيَسُبُّواْ ٱللَّهَ عَدۡوَۢا بِغَيۡرِ عِلۡمٖۗ كَذَٰلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمۡ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِم مَّرۡجِعُهُمۡ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Ẹ má ṣe bú àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kí àwọn (abọ̀rìṣà) má baà bú Allāhu ní ti àbòsí àti àìnímọ̀. Báyẹn ni A ti ṣe iṣẹ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni ibùpadàsí wọn. Nítorí náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n máa ń ṣe níṣẹ́