Surah Al-Anaam Verse 151 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaam۞قُلۡ تَعَالَوۡاْ أَتۡلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمۡ عَلَيۡكُمۡۖ أَلَّا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡـٔٗاۖ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنٗاۖ وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُم مِّنۡ إِمۡلَٰقٖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُكُمۡ وَإِيَّاهُمۡۖ وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلۡفَوَٰحِشَ مَا ظَهَرَ مِنۡهَا وَمَا بَطَنَۖ وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
So pe: "E wa ki ng ka ohun ti Oluwa yin se ni eewo fun yin; pe ki e ma se fi nnkan kan sebo si I, (ki e si se) daadaa si awon obi (yin) mejeeji, ki e si ma se pa awon omo yin nitori (iberu) osi, – Awa ni A n pese fun eyin ati awon – ki e si ma se sunmo awon iwa ibaje – eyi t’o han ninu re ati eyi t’o pamo, - ati pe ki e si ma se pa emi (eniyan) ti Allahu se ni eewo ayafi ni ona eto. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le se laakaye