Surah Al-Anaam Verse 54 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَإِذَا جَآءَكَ ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِنَا فَقُلۡ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡۖ كَتَبَ رَبُّكُمۡ عَلَىٰ نَفۡسِهِ ٱلرَّحۡمَةَ أَنَّهُۥ مَنۡ عَمِلَ مِنكُمۡ سُوٓءَۢا بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ تَابَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَصۡلَحَ فَأَنَّهُۥ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Nígbà tí àwọn t’ó gba àwọn āyah Wa gbọ́ bá wá bá ọ, sọ (fún wọn) pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Olúwa yín ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí ó ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run