Surah Al-Anaam Verse 91 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَمَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦٓ إِذۡ قَالُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَىٰ بَشَرٖ مِّن شَيۡءٖۗ قُلۡ مَنۡ أَنزَلَ ٱلۡكِتَٰبَ ٱلَّذِي جَآءَ بِهِۦ مُوسَىٰ نُورٗا وَهُدٗى لِّلنَّاسِۖ تَجۡعَلُونَهُۥ قَرَاطِيسَ تُبۡدُونَهَا وَتُخۡفُونَ كَثِيرٗاۖ وَعُلِّمۡتُم مَّا لَمۡ تَعۡلَمُوٓاْ أَنتُمۡ وَلَآ ءَابَآؤُكُمۡۖ قُلِ ٱللَّهُۖ ثُمَّ ذَرۡهُمۡ فِي خَوۡضِهِمۡ يَلۡعَبُونَ
Won ko fun Allahu ni iyi ti o to si I, nigba ti won wi pe: “Allahu ko so nnkan kan kale fun abara kan.” So pe: "Ta ni O so tira ti (Anabi) Musa mu wa kale, (eyi t’o je) imole ati imona fun awon eniyan, eyi ti e sakosile re sinu iwe ajako, ti e n se afihan re, ti e si n fi opolopo re pamo, A si fi ohun ti e o mo mo yin, eyin ati awon baba yin?" So pe: "Allahu ni." Leyin naa, fi won sile sinu isokuso won, ki won maa sere