Surah Al-Anaam Verse 94 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَلَقَدۡ جِئۡتُمُونَا فُرَٰدَىٰ كَمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَتَرَكۡتُم مَّا خَوَّلۡنَٰكُمۡ وَرَآءَ ظُهُورِكُمۡۖ وَمَا نَرَىٰ مَعَكُمۡ شُفَعَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُمۡ أَنَّهُمۡ فِيكُمۡ شُرَكَـٰٓؤُاْۚ لَقَد تَّقَطَّعَ بَيۡنَكُمۡ وَضَلَّ عَنكُم مَّا كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ
Dajudaju e ti wa ba wa ni ikookan gege bi A se seda yin nigba akoko. E si ti fi ohun ti A fun yin sile si eyin yin. A o ma ri awon olusipe yin pelu yin, awon ti e so lai ni eri pe dajudaju laaarin yin awon ni akegbe (fun Allahu). Dajudaju asepo aarin yin ti ja patapata. Ati pe ohun ti e n so nipa won (lai ni eri lowo lori isipe yin) ti dofo mo yin lowo