Surah Al-Araf Verse 141 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafوَإِذۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُقَتِّلُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ
(Ẹ rántí) nígbà tí A là yín lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, wọ́n ń pa àwọn ọmọkùnrin yín tààrà, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín