Surah Al-Araf Verse 185 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafأَوَلَمۡ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ وَأَنۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَدِ ٱقۡتَرَبَ أَجَلُهُمۡۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? “ọ̀rọ̀ wo nínú ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ ikú wọn bá dé tàbí lẹ́yìn tí ọjọ́ Àjíǹde bá ṣẹlẹ̀? Bí wọ́n bá padà gba ọ̀rọ̀ al-Ƙu’ān gbọ́ lọ́jọ́ ikú wọn tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde kò lè wúlò fún wọn mọ́ ọ̀rọ̀ irọ́ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí al-Ƙur’ān ti mú ọ̀rọ̀ òdodo wá? Ṣé àwọn ìròrí ìgbà àìmọ́kan àti àwọn àṣà àìmọ́kan èyí tí ìran ẹnì kọ̀ọ̀kan jogún bá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá ńlá wọn tí wọn kì í ṣe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ṣé àwọn ìròrí wọn àti àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọn ni wọn yóò máa lò lẹ́yìn al-Ƙur’ān? Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:6 nítorí pé gbólóhùn t’ó ṣíwájú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa bí al-Ƙur’ān ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ òdodo. Èyí wá túmọ̀ sí pé