Surah Al-Araf Verse 189 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Araf۞هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَجَعَلَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا لِيَسۡكُنَ إِلَيۡهَاۖ فَلَمَّا تَغَشَّىٰهَا حَمَلَتۡ حَمۡلًا خَفِيفٗا فَمَرَّتۡ بِهِۦۖ فَلَمَّآ أَثۡقَلَت دَّعَوَا ٱللَّهَ رَبَّهُمَا لَئِنۡ ءَاتَيۡتَنَا صَٰلِحٗا لَّنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّـٰكِرِينَ
(Allahu) Oun ni Eni t’O da yin lati ara emi eyo kan. O si da aya fun un lati ara re nitori ki o le jegbadun igbepo pelu re. Nigba ti oko sunmo iyawo re, ti o si ru eru (ato) fifuye. O si ru u kiri. Nigba ti o si diwo dise sinu tan, awon mejeeji pe Allahu Oluwa won pe: “Ti O ba fun wa ni omo rere (t’o pe ni eda), dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.”