Surah Al-Araf Verse 46 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafوَبَيۡنَهُمَا حِجَابٞۚ وَعَلَى ٱلۡأَعۡرَافِ رِجَالٞ يَعۡرِفُونَ كُلَّۢا بِسِيمَىٰهُمۡۚ وَنَادَوۡاْ أَصۡحَٰبَ ٱلۡجَنَّةِ أَن سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡۚ لَمۡ يَدۡخُلُوهَا وَهُمۡ يَطۡمَعُونَ
Gàgá yóò wà láààrin èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná. Àwọn ènìyàn kan máa wà lórí ògiri (gàgá náà), wọn yó sì dá ẹnì kọ̀ọ̀kan (ìjọ méjèèjì) mọ̀ pẹ̀lú àmì wọn. Wọn yóò pe àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Kí àlàáfíà máa bẹ fun yín.” Wọn kò ì wọ (inú) rẹ̀, wọ́n sì ti ń jẹ̀rankàn (rẹ̀)