Surah Al-Araf Verse 64 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafفَكَذَّبُوهُ فَأَنجَيۡنَٰهُ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَأَغۡرَقۡنَا ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمًا عَمِينَ
Wọ́n sì pè é lópùrọ́. Nítorí náà, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì tẹ àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ rì. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ t’ó fọ́jú (sí òdodo)