Surah Al-Anfal Verse 41 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anfal۞وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا غَنِمۡتُم مِّن شَيۡءٖ فَأَنَّ لِلَّهِ خُمُسَهُۥ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ إِن كُنتُمۡ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَىٰ عَبۡدِنَا يَوۡمَ ٱلۡفُرۡقَانِ يَوۡمَ ٱلۡتَقَى ٱلۡجَمۡعَانِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
Ẹ mọ̀ pé ohunkóhun tí ẹ bá kó ní ọrọ̀ ogun, dájúdájú ti Allāhu ni ìdá márùn-ún rẹ̀. Ó sì wà fún Òjíṣẹ́ àti ẹbí (rẹ̀) àti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá), tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa ní Ọjọ́ ìpínyà, ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé (lójú ogun Badr). Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan