Surah Al-Anfal Verse 42 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anfalإِذۡ أَنتُم بِٱلۡعُدۡوَةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُم بِٱلۡعُدۡوَةِ ٱلۡقُصۡوَىٰ وَٱلرَّكۡبُ أَسۡفَلَ مِنكُمۡۚ وَلَوۡ تَوَاعَدتُّمۡ لَٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡمِيعَٰدِ وَلَٰكِن لِّيَقۡضِيَ ٱللَّهُ أَمۡرٗا كَانَ مَفۡعُولٗا لِّيَهۡلِكَ مَنۡ هَلَكَ عَنۢ بَيِّنَةٖ وَيَحۡيَىٰ مَنۡ حَيَّ عَنۢ بَيِّنَةٖۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ
(E ranti) nigba ti eyin wa ni eti koto t’o sunmo (ilu Modinah), awon (keferi) si wa ni eti koto t’o jinna si (ilu Modinah), awon keferi kan t’o n gun nnkan igun (bo lati irin-ajo okowo), won si wa ni isale odo tiyin. Ti o ba je pe eyin ati awon keferi jo mu ojo fun ogun naa ni, eyin iba yapa adehun naa, sugbon (ogun naa sele bee) nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse; nitori ki eni ti o maa parun (sinu aigbagbo) le parun nipase eri t’o yanju, ki eni t’o si maa ye (ninu igbagbo ododo) le ye nipase eri t’o yanju. Ati pe dajudaju Allahu kuku ni Olugbo, Onimo