Surah Al-Anfal Verse 44 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anfalوَإِذۡ يُرِيكُمُوهُمۡ إِذِ ٱلۡتَقَيۡتُمۡ فِيٓ أَعۡيُنِكُمۡ قَلِيلٗا وَيُقَلِّلُكُمۡ فِيٓ أَعۡيُنِهِمۡ لِيَقۡضِيَ ٱللَّهُ أَمۡرٗا كَانَ مَفۡعُولٗاۗ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ
(Rántí) nígbà tí Ó ń fi wọ́n hàn yín pé wọ́n kéré lójú yín - nígbà tí ẹ pàdé (lójú ogun) – Ó sì mú ẹ̀yin náà kéré lójú tiwọn náà, nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí