Surah Al-Anfal Verse 48 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anfalوَإِذۡ زَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ وَقَالَ لَا غَالِبَ لَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ مِنَ ٱلنَّاسِ وَإِنِّي جَارٞ لَّكُمۡۖ فَلَمَّا تَرَآءَتِ ٱلۡفِئَتَانِ نَكَصَ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِ وَقَالَ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّنكُمۡ إِنِّيٓ أَرَىٰ مَا لَا تَرَوۡنَ إِنِّيٓ أَخَافُ ٱللَّهَۚ وَٱللَّهُ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
(Rántí) nígbà tí Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, ó sì wí pé: “Kò sí ẹni tí ó máa borí yín lónìí nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú èmi ni aládùúgbò yín.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìjọ ogun méjèèjì fojú kanra wọn, ó padà sẹ́yìn, ó sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, ó wí pé: "Dájúdájú èmi ti yọwọ́-yọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yín. Dájúdájú èmi ń rí ohun tí ẹ̀yin kò rí. Èmi ń pàyà Allāhu. Allāhu sì le níbi ìyà