Surah Al-Anfal Verse 72 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anfalإِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَواْ وَّنَصَرُوٓاْ أُوْلَـٰٓئِكَ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۚ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَمۡ يُهَاجِرُواْ مَا لَكُم مِّن وَلَٰيَتِهِم مِّن شَيۡءٍ حَتَّىٰ يُهَاجِرُواْۚ وَإِنِ ٱسۡتَنصَرُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ فَعَلَيۡكُمُ ٱلنَّصۡرُ إِلَّا عَلَىٰ قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu, ati awon t’o gba won sodo (ninu ilu), ti won si ran won lowo; awon wonyen, apa kan won l’ore apa kan (t’o le jogun ara won). Awon t’o gbagbo, ti won ko si gbe ilu won ju sile, ko letoo fun yin lati mu won loree nibi kan kan (t’o le mu yin jogun ara yin), titi won yoo fi gbe ilu won ju sile. Ti won ba si wa iranlowo yin (lori ota) nipa esin, iranlowo naa di dandan fun yin ayafi lori ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise