Surah At-Taubah Verse 3 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah At-Taubahوَأَذَٰنٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦٓ إِلَى ٱلنَّاسِ يَوۡمَ ٱلۡحَجِّ ٱلۡأَكۡبَرِ أَنَّ ٱللَّهَ بَرِيٓءٞ مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ وَرَسُولُهُۥۚ فَإِن تُبۡتُمۡ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۖ وَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُمۡ غَيۡرُ مُعۡجِزِي ٱللَّهِۗ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Ìkéde kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Hajj Ńlá ni pé, “Dájúdájú Allāhu yọwọ́yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀) àwọn ọ̀ṣẹbọ. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ náà (yọwọ́yọsẹ̀). Tí ẹ bá ronú pìwàdà, ó sì lóore jùlọ fun yín. Tí ẹ bá gbúnrí, ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ ò lè móríbọ́ nínú (ìyà) Allāhu.” Kí o sì fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro