Surah At-Taubah Verse 38 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah At-Taubahيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَا لَكُمۡ إِذَا قِيلَ لَكُمُ ٱنفِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱثَّاقَلۡتُمۡ إِلَى ٱلۡأَرۡضِۚ أَرَضِيتُم بِٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا مِنَ ٱلۡأٓخِرَةِۚ فَمَا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِلَّا قَلِيلٌ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí ni ó mu yín tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí A bá sọ fun yín pé kí ẹ jáde (láti jagun) lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (ìgbà náà ni) ẹ máa kàndí mọ́lẹ̀! Ṣé ẹ yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ju ti ọ̀run ni? Ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé (yìí) kò sì jẹ́ kiní kan nínú ti ọ̀run àfi díẹ̀