Surah At-Taubah Verse 40 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah At-Taubahإِلَّا تَنصُرُوهُ فَقَدۡ نَصَرَهُ ٱللَّهُ إِذۡ أَخۡرَجَهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ثَانِيَ ٱثۡنَيۡنِ إِذۡ هُمَا فِي ٱلۡغَارِ إِذۡ يَقُولُ لِصَٰحِبِهِۦ لَا تَحۡزَنۡ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَنَاۖ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَيۡهِ وَأَيَّدَهُۥ بِجُنُودٖ لَّمۡ تَرَوۡهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلسُّفۡلَىٰۗ وَكَلِمَةُ ٱللَّهِ هِيَ ٱلۡعُلۡيَاۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.1 Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa."2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ ò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun l’ó sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n