Surah At-Taubah Verse 80 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah At-Taubahٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ أَوۡ لَا تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ إِن تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ سَبۡعِينَ مَرَّةٗ فَلَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَفَرُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn – kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin – Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́