Surah At-Taubah Verse 99 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah At-Taubahوَمِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مَن يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ قُرُبَٰتٍ عِندَ ٱللَّهِ وَصَلَوَٰتِ ٱلرَّسُولِۚ أَلَآ إِنَّهَا قُرۡبَةٞ لَّهُمۡۚ سَيُدۡخِلُهُمُ ٱللَّهُ فِي رَحۡمَتِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) di àwọn ìsúnmọ́ Allāhu àti (gbígba) àdùá (lọ́dọ̀) Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú òhun ni ìsúnmọ́ Allāhu fún wọn. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run