Surah Al-Qadr - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةِ ٱلۡقَدۡرِ
Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì
Surah Al-Qadr, Verse 1
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Òru Abiyì
Surah Al-Qadr, Verse 2
لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ خَيۡرٞ مِّنۡ أَلۡفِ شَهۡرٖ
Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù lọ
Surah Al-Qadr, Verse 3
تَنَزَّلُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ فِيهَا بِإِذۡنِ رَبِّهِم مِّن كُلِّ أَمۡرٖ
Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan
Surah Al-Qadr, Verse 4
سَلَٰمٌ هِيَ حَتَّىٰ مَطۡلَعِ ٱلۡفَجۡرِ
Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́
Surah Al-Qadr, Verse 5