UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Ibrahim - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


الٓرۚ كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ إِلَيۡكَ لِتُخۡرِجَ ٱلنَّاسَ مِنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ بِإِذۡنِ رَبِّهِمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ

’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè mú àwọn ènìyàn kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa wọn. (Wọn yó sì bọ́) sí ọ̀nà Alágbára, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí)
Surah Ibrahim, Verse 1


ٱللَّهِ ٱلَّذِي لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَوَيۡلٞ لِّلۡكَٰفِرِينَ مِنۡ عَذَابٖ شَدِيدٍ

Allāhu, Ẹni tí Ó ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ègbé ni fún àwọn aláìgbàgbọ́ níbi ìyà líle
Surah Ibrahim, Verse 2


ٱلَّذِينَ يَسۡتَحِبُّونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا عَلَى ٱلۡأٓخِرَةِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَيَبۡغُونَهَا عِوَجًاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلِۭ بَعِيدٖ

Àwọn t’ó ń fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju tọ̀run, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́; àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà t’ó jìnnà
Surah Ibrahim, Verse 3


وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوۡمِهِۦ لِيُبَيِّنَ لَهُمۡۖ فَيُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè ìjọ rẹ̀1 nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Ibrahim, Verse 4


وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَآ أَنۡ أَخۡرِجۡ قَوۡمَكَ مِنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ وَذَكِّرۡهُم بِأَيَّىٰمِ ٱللَّهِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ

A kúkú fi àwọn āyah Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ pé: “Mú ìjọ rẹ kúrò láti inú àwọn òkùnkùn bọ́ sínú ìmólẹ̀. Kí o sì rán wọn létí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu (lórí wọn).” Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́
Surah Ibrahim, Verse 5


وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ أَنجَىٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ وَيُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé ẹ rántí ìkẹ́ Allāhu lórí yín nígbà tí Ó gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín; wọ́n ń dúnńbú àwọn ọmọkùnrin yín, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín
Surah Ibrahim, Verse 6


وَإِذۡ تَأَذَّنَ رَبُّكُمۡ لَئِن شَكَرۡتُمۡ لَأَزِيدَنَّكُمۡۖ وَلَئِن كَفَرۡتُمۡ إِنَّ عَذَابِي لَشَدِيدٞ

(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa Ẹlẹ́dàá yín sọ ọ́ di mímọ̀ (fun yín pé): "Dájúdájú tí ẹ bá dúpẹ́, Èmi yóò ṣàlékún fun yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣàìmoore, dájúdájú ìyà Mi mà le
Surah Ibrahim, Verse 7


وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِن تَكۡفُرُوٓاْ أَنتُمۡ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا فَإِنَّ ٱللَّهَ لَغَنِيٌّ حَمِيدٌ

(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Tí ẹ bá ṣàìmoore, ẹ̀yin àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́
Surah Ibrahim, Verse 8


أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ نَبَؤُاْ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا ٱللَّهُۚ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرَدُّوٓاْ أَيۡدِيَهُمۡ فِيٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَقَالُوٓاْ إِنَّا كَفَرۡنَا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ وَإِنَّا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَنَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ

Ṣé ìró àwọn t’ó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n ti ọwọ́ wọn bọ ẹnu wọn (ní ti ìbínú), wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí
Surah Ibrahim, Verse 9


۞قَالَتۡ رُسُلُهُمۡ أَفِي ٱللَّهِ شَكّٞ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يَدۡعُوكُمۡ لِيَغۡفِرَ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُؤَخِّرَكُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ قَالُوٓاْ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا تُرِيدُونَ أَن تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا فَأۡتُونَا بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ

Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ pé: “Ṣé iyèméjì kan ń bẹ níbi (bíbẹ) Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó ń pè yín nítorí kí Ó lè forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín àti nítorí kí Ó lè lọ yín lára di gbèdéke àkókò kan.” Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan tayọ abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.”
Surah Ibrahim, Verse 10


قَالَتۡ لَهُمۡ رُسُلُهُمۡ إِن نَّحۡنُ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَمُنُّ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۖ وَمَا كَانَ لَنَآ أَن نَّأۡتِيَكُم بِسُلۡطَٰنٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ

Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: “Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fun yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé, Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé
Surah Ibrahim, Verse 11


وَمَا لَنَآ أَلَّا نَتَوَكَّلَ عَلَى ٱللَّهِ وَقَدۡ هَدَىٰنَا سُبُلَنَاۚ وَلَنَصۡبِرَنَّ عَلَىٰ مَآ ءَاذَيۡتُمُونَاۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُتَوَكِّلُونَ

Kí ni ó máa ṣe wá tí a ò níí gbáralé Allāhu, Ó kúkú ti fi àwọn ọ̀nà wa mọ̀ wá. Dájúdájú a máa ṣe sùúrù lórí ohun tí ẹ bá fi kó ìnira bá wa. Allāhu sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”
Surah Ibrahim, Verse 12


وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِرُسُلِهِمۡ لَنُخۡرِجَنَّكُم مِّنۡ أَرۡضِنَآ أَوۡ لَتَعُودُنَّ فِي مِلَّتِنَاۖ فَأَوۡحَىٰٓ إِلَيۡهِمۡ رَبُّهُمۡ لَنُهۡلِكَنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn Òjíṣẹ́ wọn pé: “Dájúdájú àwa yóò le yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa tàbí kí ẹ kúkú padà sínú ẹ̀sìn wa.” Nígbà náà, Olúwa wọn fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn pé: “Dájúdájú A máa pa àwọn alábòsí run
Surah Ibrahim, Verse 13


وَلَنُسۡكِنَنَّكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَافَ مَقَامِي وَخَافَ وَعِيدِ

Dájúdájú A sì máa fun yín ní ibùgbé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn. ” Ìyẹn wà fún ẹni tí ó bá páyà ìdúró (níwájú) Mi, tí ó tún páyà ìlérí Mi
Surah Ibrahim, Verse 14


وَٱسۡتَفۡتَحُواْ وَخَابَ كُلُّ جَبَّارٍ عَنِيدٖ

Wọ́n sì tọrọ àrànṣe (Allāhu lórí ìjọ wọn). Gbogbo aláfojúdi, olóríkunkun sì pàdánù
Surah Ibrahim, Verse 15


مِّن وَرَآئِهِۦ جَهَنَّمُ وَيُسۡقَىٰ مِن مَّآءٖ صَدِيدٖ

Iná Jahanamọ ń bẹ lẹ́yìn (ìparun) rẹ̀; A ó sì máa fún un ní omi àwọyúnwẹ̀jẹ̀ mu
Surah Ibrahim, Verse 16


يَتَجَرَّعُهُۥ وَلَا يَكَادُ يُسِيغُهُۥ وَيَأۡتِيهِ ٱلۡمَوۡتُ مِن كُلِّ مَكَانٖ وَمَا هُوَ بِمَيِّتٖۖ وَمِن وَرَآئِهِۦ عَذَابٌ غَلِيظٞ

Ó máa sáré mu ún díẹ̀díẹ̀, kò sì níí fẹ́ẹ̀ lè gbé e mì. (Ìnira) ikú yó sì máa yọ sí i ní gbogbo àyè, síbẹ̀ kò níí kú. Ìyà t’ó nípọn tún wà fún un lẹ́yìn rẹ̀
Surah Ibrahim, Verse 17


مَّثَلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِرَبِّهِمۡۖ أَعۡمَٰلُهُمۡ كَرَمَادٍ ٱشۡتَدَّتۡ بِهِ ٱلرِّيحُ فِي يَوۡمٍ عَاصِفٖۖ لَّا يَقۡدِرُونَ مِمَّا كَسَبُواْ عَلَىٰ شَيۡءٖۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلضَّلَٰلُ ٱلۡبَعِيدُ

Àfiwé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn: àwọn iṣẹ́ wọn dà bí eérú tí atẹ́gùn fẹ́ dànù pátápátá ní ọjọ́ ìjì atẹ́gùn. Wọn kò ní agbára kan lórí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ìyẹn ni ìṣìnà t’ó jìnnà
Surah Ibrahim, Verse 18


أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ إِن يَشَأۡ يُذۡهِبۡكُمۡ وَيَأۡتِ بِخَلۡقٖ جَدِيدٖ

Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo? Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá
Surah Ibrahim, Verse 19


وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ بِعَزِيزٖ

Ìyẹn kò sì lè dá Allāhu lágara
Surah Ibrahim, Verse 20


وَبَرَزُواْ لِلَّهِ جَمِيعٗا فَقَالَ ٱلضُّعَفَـٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعٗا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا مِنۡ عَذَابِ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۚ قَالُواْ لَوۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُ لَهَدَيۡنَٰكُمۡۖ سَوَآءٌ عَلَيۡنَآ أَجَزِعۡنَآ أَمۡ صَبَرۡنَا مَا لَنَا مِن مَّحِيصٖ

Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?” Wọn yóò wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa.”
Surah Ibrahim, Verse 21


وَقَالَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لَمَّا قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ إِنَّ ٱللَّهَ وَعَدَكُمۡ وَعۡدَ ٱلۡحَقِّ وَوَعَدتُّكُمۡ فَأَخۡلَفۡتُكُمۡۖ وَمَا كَانَ لِيَ عَلَيۡكُم مِّن سُلۡطَٰنٍ إِلَّآ أَن دَعَوۡتُكُمۡ فَٱسۡتَجَبۡتُمۡ لِيۖ فَلَا تَلُومُونِي وَلُومُوٓاْ أَنفُسَكُمۖ مَّآ أَنَا۠ بِمُصۡرِخِكُمۡ وَمَآ أَنتُم بِمُصۡرِخِيَّ إِنِّي كَفَرۡتُ بِمَآ أَشۡرَكۡتُمُونِ مِن قَبۡلُۗ إِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Èṣù yó sì wí nígbà tí A bá ṣèdájọ́ (ẹ̀dá) tán, pé: “Dájúdájú Allāhu ṣe àdéhùn fun yín ní àdéhùn òdodo. Èmi náà ṣe àdéhùn fun yín. Mo sì yapa àdéhùn tí mo ṣe fun yín. Èmi kò sì ní agbára kan lórí yín bí kò ṣe pé mo pè yín ẹ sì jẹ́pè mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe bú mi; ara yín ni kí ẹ bú. Èmi kò lè ràn yín lọ́wọ́ (níbi ìyà), Ẹ̀yin náà kò sì lè ràn mí lọ́wọ́ (níbi ìyà). Dájúdájú èmi ti lòdì sí ohun tí ẹ fi sọ mí di akẹgbẹ́ Allāhu ṣíwájú.” Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn
Surah Ibrahim, Verse 22


وَأُدۡخِلَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا بِإِذۡنِ رَبِّهِمۡۖ تَحِيَّتُهُمۡ فِيهَا سَلَٰمٌ

Wọ́n sì máa mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni ‘àlàáfíà’
Surah Ibrahim, Verse 23


أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا كَلِمَةٗ طَيِّبَةٗ كَشَجَرَةٖ طَيِّبَةٍ أَصۡلُهَا ثَابِتٞ وَفَرۡعُهَا فِي ٱلسَّمَآءِ

Ṣé o ò rí bí Allāhu ti ṣàkàwé ọ̀rọ̀ dáadáa pẹ̀lú igi dáadáa, tí gbòǹgbò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tí ẹka rẹ̀ sì wà nínú sánmọ̀
Surah Ibrahim, Verse 24


تُؤۡتِيٓ أُكُلَهَا كُلَّ حِينِۭ بِإِذۡنِ رَبِّهَاۗ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَالَ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ

tó sì ń so èso (jíjẹ) rẹ̀ ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀? Allāhu ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn àkàwé nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí
Surah Ibrahim, Verse 25


وَمَثَلُ كَلِمَةٍ خَبِيثَةٖ كَشَجَرَةٍ خَبِيثَةٍ ٱجۡتُثَّتۡ مِن فَوۡقِ ٱلۡأَرۡضِ مَا لَهَا مِن قَرَارٖ

Àkàwé ọ̀rọ̀ tí kò dára sì dà bí igi tí kò dára, tí wọ́n fà tu láti òkè lórí ilẹ̀, tí kò sì ní àyè kan lórí ilẹ̀
Surah Ibrahim, Verse 26


يُثَبِّتُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱلۡقَوۡلِ ٱلثَّابِتِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۖ وَيُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلظَّـٰلِمِينَۚ وَيَفۡعَلُ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ

Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ó sì máa ṣi àwọn alábòsí lọ́nà. Àti pé Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́
Surah Ibrahim, Verse 27


۞أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ بَدَّلُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ كُفۡرٗا وَأَحَلُّواْ قَوۡمَهُمۡ دَارَ ٱلۡبَوَارِ

Ṣé o ò rí àwọn t’ó yí ìdẹ̀ra Allāhu padà sí àìgbàgbọ́, tí wọ́n sì mú ìjọ wọn gúnlẹ̀ sí ilé ìparun
Surah Ibrahim, Verse 28


جَهَنَّمَ يَصۡلَوۡنَهَاۖ وَبِئۡسَ ٱلۡقَرَارُ

Iná Jahanamọ ni wọn yóò gúnlẹ̀ sí; ibùgbé náà sì burú
Surah Ibrahim, Verse 29


وَجَعَلُواْ لِلَّهِ أَندَادٗا لِّيُضِلُّواْ عَن سَبِيلِهِۦۗ قُلۡ تَمَتَّعُواْ فَإِنَّ مَصِيرَكُمۡ إِلَى ٱلنَّارِ

Wọ́n sọ (àwọn kan di) akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò nínú ẹ̀sìn Rẹ̀. Sọ pé: “Ẹ máa gbádùn ǹsó, nítorí pé dájúdájú àbọ̀ yín ni Iná.”
Surah Ibrahim, Verse 30


قُل لِّعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُنفِقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا بَيۡعٞ فِيهِ وَلَا خِلَٰلٌ

Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò níí sí títà-rírà kan àti yíyan ọ̀rẹ́ kan nínú rẹ̀
Surah Ibrahim, Verse 31


ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجَ بِهِۦ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ رِزۡقٗا لَّكُمۡۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡفُلۡكَ لِتَجۡرِيَ فِي ٱلۡبَحۡرِ بِأَمۡرِهِۦۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡهَٰرَ

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì fi ń mú àwọn èso jáde; (ó jẹ́) arísìkí fun yín. Ó sì rọ ọkọ̀ ojú-omi fun yín kí ó lè rìn lójú omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Ó tún rọ àwọn odò fun yín
Surah Ibrahim, Verse 32


وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ دَآئِبَيۡنِۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ

Ó rọ òòrùn àti òṣùpá fun yín, tí méjèèjì ń rìn láì sinmi. Ó tún rọ òru àti ọ̀sán fun yín
Surah Ibrahim, Verse 33


وَءَاتَىٰكُم مِّن كُلِّ مَا سَأَلۡتُمُوهُۚ وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَظَلُومٞ كَفَّارٞ

Àti pé Ó ń fun yín nínú gbogbo n̄ǹkan tí ẹ tọrọ lọ́dọ̀ Rẹ̀. Tí ẹ bá ṣe òǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú ènìyàn ni alábòsí aláìmoore
Surah Ibrahim, Verse 34


وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ رَبِّ ٱجۡعَلۡ هَٰذَا ٱلۡبَلَدَ ءَامِنٗا وَٱجۡنُبۡنِي وَبَنِيَّ أَن نَّعۡبُدَ ٱلۡأَصۡنَامَ

(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì mú èmi àti àwọn ọmọ mi jìnnà sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà
Surah Ibrahim, Verse 35


رَبِّ إِنَّهُنَّ أَضۡلَلۡنَ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِۖ فَمَن تَبِعَنِي فَإِنَّهُۥ مِنِّيۖ وَمَنۡ عَصَانِي فَإِنَّكَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Olúwa mi, dájúdájú àwọn òrìṣà ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn sọnù. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé mi, dájúdájú òun ni ẹni mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa mi, dájúdájú Ìwọ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́
Surah Ibrahim, Verse 36


رَّبَّنَآ إِنِّيٓ أَسۡكَنتُ مِن ذُرِّيَّتِي بِوَادٍ غَيۡرِ ذِي زَرۡعٍ عِندَ بَيۡتِكَ ٱلۡمُحَرَّمِ رَبَّنَا لِيُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ فَٱجۡعَلۡ أَفۡـِٔدَةٗ مِّنَ ٱلنَّاسِ تَهۡوِيٓ إِلَيۡهِمۡ وَٱرۡزُقۡهُم مِّنَ ٱلثَّمَرَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَشۡكُرُونَ

Olúwa wa, dájúdájú èmi wá ibùgbé fún àrọ́mọdọ́mọ mi sí ilẹ̀ àfonífojì, ilẹ̀ tí kò ní èso, nítòsí Ilé Rẹ Ọlọ́wọ̀. Olúwa wa, nítorí kí wọ́n lè kírun ni. Nítorí náà, jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn fà sọ́dọ̀ wọn. Kí O sì pèsè àwọn èso fún wọn nítorí kí wọ́n lè dúpẹ́ (fún Ọ)
Surah Ibrahim, Verse 37


رَبَّنَآ إِنَّكَ تَعۡلَمُ مَا نُخۡفِي وَمَا نُعۡلِنُۗ وَمَا يَخۡفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ

Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O mọ ohun tí à ń fi pamọ́ àti ohun tí à ń ṣe àfihàn rẹ̀. Kò sì sí kiní kan nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀ t’ó pamọ́ fún Allāhu
Surah Ibrahim, Verse 38


ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي وَهَبَ لِي عَلَى ٱلۡكِبَرِ إِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَۚ إِنَّ رَبِّي لَسَمِيعُ ٱلدُّعَآءِ

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún mi ní ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ nígbà tí mo ti darúgbó. Dájúdájú, Olúwa mi ni Olùgbọ́ àdúà
Surah Ibrahim, Verse 39


رَبِّ ٱجۡعَلۡنِي مُقِيمَ ٱلصَّلَوٰةِ وَمِن ذُرِّيَّتِيۚ رَبَّنَا وَتَقَبَّلۡ دُعَآءِ

Olúwa mi, ṣe èmi àti nínú àrọ́mọdọ́mọ mi ni olùkírun. Olúwa wa, kí O sì gba àdúà mi
Surah Ibrahim, Verse 40


رَبَّنَا ٱغۡفِرۡ لِي وَلِوَٰلِدَيَّ وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ يَوۡمَ يَقُومُ ٱلۡحِسَابُ

Olúwa mi, ṣàforíjìn fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọjọ́ tí ìṣírò-iṣẹ́ yóò ṣẹlẹ̀
Surah Ibrahim, Verse 41


وَلَا تَحۡسَبَنَّ ٱللَّهَ غَٰفِلًا عَمَّا يَعۡمَلُ ٱلظَّـٰلِمُونَۚ إِنَّمَا يُؤَخِّرُهُمۡ لِيَوۡمٖ تَشۡخَصُ فِيهِ ٱلۡأَبۡصَٰرُ

Má ṣe lérò pé Allāhu gbàgbé n̄ǹkan tí àwọn alábòsí ń ṣe níṣẹ́. Ó kàn ń lọ́ wọn lára dí ọjọ́ kan tí àwọn ojú yóò yọ síta ràngàndàn
Surah Ibrahim, Verse 42


مُهۡطِعِينَ مُقۡنِعِي رُءُوسِهِمۡ لَا يَرۡتَدُّ إِلَيۡهِمۡ طَرۡفُهُمۡۖ وَأَفۡـِٔدَتُهُمۡ هَوَآءٞ

Wọn yóò má sáré (lọ síbi àkójọ fún ìṣírò-iṣẹ́), wọn yóò gbé orí wọn sókè, ìpéǹpéjú wọn kò sì níí padà sọ́dọ̀ wọn, àwọn ọkàn wọn yó sì pa sófo pátápátá (fún ìbẹ̀rù)
Surah Ibrahim, Verse 43


وَأَنذِرِ ٱلنَّاسَ يَوۡمَ يَأۡتِيهِمُ ٱلۡعَذَابُ فَيَقُولُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ رَبَّنَآ أَخِّرۡنَآ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖ نُّجِبۡ دَعۡوَتَكَ وَنَتَّبِعِ ٱلرُّسُلَۗ أَوَلَمۡ تَكُونُوٓاْ أَقۡسَمۡتُم مِّن قَبۡلُ مَا لَكُم مِّن زَوَالٖ

Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, àwọn t’ó ṣàbòsí yó sì wí pé: “Olúwa wa, lọ́ wa lára fún àsìkò díẹ̀ sí i, a máa jẹ́pè Rẹ, a sì máa tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́.” Ṣé ẹ̀yin kò ti búra ṣíwájú pé ẹ̀yin kò níí kúrò nílé ayé ni
Surah Ibrahim, Verse 44


وَسَكَنتُمۡ فِي مَسَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَتَبَيَّنَ لَكُمۡ كَيۡفَ فَعَلۡنَا بِهِمۡ وَضَرَبۡنَا لَكُمُ ٱلۡأَمۡثَالَ

Ẹ sì gbé nínú ibùgbé àwọn t’ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Ó sì hàn si yín bí A ti ṣe pẹ̀lú wọn. A tún fun yín ni àwọn àkàwé
Surah Ibrahim, Verse 45


وَقَدۡ مَكَرُواْ مَكۡرَهُمۡ وَعِندَ ٱللَّهِ مَكۡرُهُمۡ وَإِن كَانَ مَكۡرُهُمۡ لِتَزُولَ مِنۡهُ ٱلۡجِبَالُ

Wọ́n kúkú ti dá ète wọn, ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ète wọn wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé (pẹ̀lú) ète wọn àpáta fẹ́ẹ̀ lè yẹ̀ lulẹ̀
Surah Ibrahim, Verse 46


فَلَا تَحۡسَبَنَّ ٱللَّهَ مُخۡلِفَ وَعۡدِهِۦ رُسُلَهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٖ

Nítorí náà, má ṣe lérò pé Allāhu yóò yapa àdéhùn Rẹ̀ tí Ó ṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùgbẹ̀san
Surah Ibrahim, Verse 47


يَوۡمَ تُبَدَّلُ ٱلۡأَرۡضُ غَيۡرَ ٱلۡأَرۡضِ وَٱلسَّمَٰوَٰتُۖ وَبَرَزُواْ لِلَّهِ ٱلۡوَٰحِدِ ٱلۡقَهَّارِ

Ní ọjọ́ tí A máa yí ilẹ̀ ayé padà sì n̄ǹkan mìíràn. (A máa yí) àwọn sánmọ̀ náà (padà. Àwọn ẹ̀dá) sì máa jáde (síwájú) Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí
Surah Ibrahim, Verse 48


وَتَرَى ٱلۡمُجۡرِمِينَ يَوۡمَئِذٖ مُّقَرَّنِينَ فِي ٱلۡأَصۡفَادِ

O sì máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí wọn yóò so wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn sínú sẹ́kẹ́sẹkẹ̀
Surah Ibrahim, Verse 49


سَرَابِيلُهُم مِّن قَطِرَانٖ وَتَغۡشَىٰ وُجُوهَهُمُ ٱلنَّارُ

Òjé Iná ni àwọn èwù wọn. Iná yó sì bo ojú wọn mọ́lẹ̀ bámúbámú
Surah Ibrahim, Verse 50


لِيَجۡزِيَ ٱللَّهُ كُلَّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ

nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́
Surah Ibrahim, Verse 51


هَٰذَا بَلَٰغٞ لِّلنَّاسِ وَلِيُنذَرُواْ بِهِۦ وَلِيَعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ وَلِيَذَّكَّرَ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ

Èyí ni iṣẹ́-jíjẹ́ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè fi ṣe ìkìlọ̀, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé (Allāhu) Òun nìkan ni Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí, Ọ̀kan ṣoṣo, àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí
Surah Ibrahim, Verse 52


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 13
>> Surah 15

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai