Surah Al-Hijr - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ وَقُرۡءَانٖ مُّبِينٖ
’Alif lām rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá
Surah Al-Hijr, Verse 1
رُّبَمَا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ كَانُواْ مُسۡلِمِينَ
Ó ṣeé ṣe kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé)
Surah Al-Hijr, Verse 2
ذَرۡهُمۡ يَأۡكُلُواْ وَيَتَمَتَّعُواْ وَيُلۡهِهِمُ ٱلۡأَمَلُۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 3
وَمَآ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٞ مَّعۡلُومٞ
A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 4
مَّا تَسۡبِقُ مِنۡ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ
Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn
Surah Al-Hijr, Verse 5
وَقَالُواْ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِي نُزِّلَ عَلَيۡهِ ٱلذِّكۡرُ إِنَّكَ لَمَجۡنُونٞ
Wọ́n wí pé: “Ìwọ tí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ẹ́
Surah Al-Hijr, Verse 6
لَّوۡمَا تَأۡتِينَا بِٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Kí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”
Surah Al-Hijr, Verse 7
مَا نُنَزِّلُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَمَا كَانُوٓاْ إِذٗا مُّنظَرِينَ
A ò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀)
Surah Al-Hijr, Verse 8
إِنَّا نَحۡنُ نَزَّلۡنَا ٱلذِّكۡرَ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Dájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 9
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي شِيَعِ ٱلۡأَوَّلِينَ
Dájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́
Surah Al-Hijr, Verse 10
وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Òjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́
Surah Al-Hijr, Verse 11
كَذَٰلِكَ نَسۡلُكُهُۥ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ
Báyẹn ni A ṣe ń fi (àìsàn) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 12
لَا يُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَقَدۡ خَلَتۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Wọn kò níí gba Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbọ́; ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá
Surah Al-Hijr, Verse 13
وَلَوۡ فَتَحۡنَا عَلَيۡهِم بَابٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَظَلُّواْ فِيهِ يَعۡرُجُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀)
Surah Al-Hijr, Verse 14
لَقَالُوٓاْ إِنَّمَا سُكِّرَتۡ أَبۡصَٰرُنَا بَلۡ نَحۡنُ قَوۡمٞ مَّسۡحُورُونَ
dájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kúkú lo ìṣíjú fún wa ni. Ńṣe ni wọ́n ń dan wá.”
Surah Al-Hijr, Verse 15
وَلَقَدۡ جَعَلۡنَا فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَزَيَّنَّـٰهَا لِلنَّـٰظِرِينَ
A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ (ìràwọ̀) sínú sánmọ̀ (ayé). A sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran
Surah Al-Hijr, Verse 16
وَحَفِظۡنَٰهَا مِن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ رَّجِيمٍ
A sì fi ààbò bo ìmísí sánmọ̀ lọ́dọ̀ gbogbo èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 17
إِلَّا مَنِ ٱسۡتَرَقَ ٱلسَّمۡعَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ مُّبِينٞ
Àfi (èṣù) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn
Surah Al-Hijr, Verse 18
وَٱلۡأَرۡضَ مَدَدۡنَٰهَا وَأَلۡقَيۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ شَيۡءٖ مَّوۡزُونٖ
Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 19
وَجَعَلۡنَا لَكُمۡ فِيهَا مَعَٰيِشَ وَمَن لَّسۡتُمۡ لَهُۥ بِرَٰزِقِينَ
A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún
Surah Al-Hijr, Verse 20
وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا عِندَنَا خَزَآئِنُهُۥ وَمَا نُنَزِّلُهُۥٓ إِلَّا بِقَدَرٖ مَّعۡلُومٖ
Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 21
وَأَرۡسَلۡنَا ٱلرِّيَٰحَ لَوَٰقِحَ فَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَسۡقَيۡنَٰكُمُوهُ وَمَآ أَنتُمۡ لَهُۥ بِخَٰزِنِينَ
Àti pé A rán atẹ́gùn láti kó ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fun yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀)
Surah Al-Hijr, Verse 22
وَإِنَّا لَنَحۡنُ نُحۡيِۦ وَنُمِيتُ وَنَحۡنُ ٱلۡوَٰرِثُونَ
Dájúdájú Àwa, Àwa mà l’À ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá)
Surah Al-Hijr, Verse 23
وَلَقَدۡ عَلِمۡنَا ٱلۡمُسۡتَقۡدِمِينَ مِنكُمۡ وَلَقَدۡ عَلِمۡنَا ٱلۡمُسۡتَـٔۡخِرِينَ
Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn
Surah Al-Hijr, Verse 24
وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحۡشُرُهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 25
وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà
Surah Al-Hijr, Verse 26
وَٱلۡجَآنَّ خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ مِن نَّارِ ٱلسَّمُومِ
Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín
Surah Al-Hijr, Verse 27
وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِنِّي خَٰلِقُۢ بَشَرٗا مِّن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà
Surah Al-Hijr, Verse 28
فَإِذَا سَوَّيۡتُهُۥ وَنَفَخۡتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُۥ سَٰجِدِينَ
Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó gún régé tán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni
Surah Al-Hijr, Verse 29
فَسَجَدَ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ كُلُّهُمۡ أَجۡمَعُونَ
Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i
Surah Al-Hijr, Verse 30
إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰٓ أَن يَكُونَ مَعَ ٱلسَّـٰجِدِينَ
Àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ náà
Surah Al-Hijr, Verse 31
قَالَ يَـٰٓإِبۡلِيسُ مَا لَكَ أَلَّا تَكُونَ مَعَ ٱلسَّـٰجِدِينَ
(Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 32
قَالَ لَمۡ أَكُن لِّأَسۡجُدَ لِبَشَرٍ خَلَقۡتَهُۥ مِن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ
Ó wí pé: "Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà
Surah Al-Hijr, Verse 33
قَالَ فَٱخۡرُجۡ مِنۡهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٞ
(Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 34
وَإِنَّ عَلَيۡكَ ٱللَّعۡنَةَ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلدِّينِ
Àti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san
Surah Al-Hijr, Verse 35
قَالَ رَبِّ فَأَنظِرۡنِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ
Ó wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ Àjíǹde.”
Surah Al-Hijr, Verse 36
قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ ٱلۡمُنظَرِينَ
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára
Surah Al-Hijr, Verse 37
إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡوَقۡتِ ٱلۡمَعۡلُومِ
títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ
Surah Al-Hijr, Verse 38
قَالَ رَبِّ بِمَآ أَغۡوَيۡتَنِي لَأُزَيِّنَنَّ لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَأُغۡوِيَنَّهُمۡ أَجۡمَعِينَ
Ó wí pé: "Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù
Surah Al-Hijr, Verse 39
إِلَّا عِبَادَكَ مِنۡهُمُ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn
Surah Al-Hijr, Verse 40
قَالَ هَٰذَا صِرَٰطٌ عَلَيَّ مُسۡتَقِيمٌ
(Allāhu) sọ pé: "(Ìdúróṣinṣin lójú) ọ̀nà tààrà, Ọwọ́ Mi ni èyí wà
Surah Al-Hijr, Verse 41
إِنَّ عِبَادِي لَيۡسَ لَكَ عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٌ إِلَّا مَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلۡغَاوِينَ
Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù
Surah Al-Hijr, Verse 42
وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمَوۡعِدُهُمۡ أَجۡمَعِينَ
Àti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn
Surah Al-Hijr, Verse 43
لَهَا سَبۡعَةُ أَبۡوَٰبٖ لِّكُلِّ بَابٖ مِّنۡهُمۡ جُزۡءٞ مَّقۡسُومٌ
Àwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan
Surah Al-Hijr, Verse 44
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّـٰتٖ وَعُيُونٍ
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀)
Surah Al-Hijr, Verse 45
ٱدۡخُلُوهَا بِسَلَٰمٍ ءَامِنِينَ
(A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”
Surah Al-Hijr, Verse 46
وَنَزَعۡنَا مَا فِي صُدُورِهِم مِّنۡ غِلٍّ إِخۡوَٰنًا عَلَىٰ سُرُرٖ مُّتَقَٰبِلِينَ
A sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn t’ó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn
Surah Al-Hijr, Verse 47
لَا يَمَسُّهُمۡ فِيهَا نَصَبٞ وَمَا هُم مِّنۡهَا بِمُخۡرَجِينَ
Wàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 48
۞نَبِّئۡ عِبَادِيٓ أَنِّيٓ أَنَا ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Hijr, Verse 49
وَأَنَّ عَذَابِي هُوَ ٱلۡعَذَابُ ٱلۡأَلِيمُ
Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro
Surah Al-Hijr, Verse 50
وَنَبِّئۡهُمۡ عَن ضَيۡفِ إِبۡرَٰهِيمَ
Fún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm
Surah Al-Hijr, Verse 51
إِذۡ دَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَقَالُواْ سَلَٰمٗا قَالَ إِنَّا مِنكُمۡ وَجِلُونَ
(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”
Surah Al-Hijr, Verse 52
قَالُواْ لَا تَوۡجَلۡ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ عَلِيمٖ
Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin onímímọ̀ kan
Surah Al-Hijr, Verse 53
قَالَ أَبَشَّرۡتُمُونِي عَلَىٰٓ أَن مَّسَّنِيَ ٱلۡكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná
Surah Al-Hijr, Verse 54
قَالُواْ بَشَّرۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ فَلَا تَكُن مِّنَ ٱلۡقَٰنِطِينَ
Wọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”
Surah Al-Hijr, Verse 55
قَالَ وَمَن يَقۡنَطُ مِن رَّحۡمَةِ رَبِّهِۦٓ إِلَّا ٱلضَّآلُّونَ
Ó sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”
Surah Al-Hijr, Verse 56
قَالَ فَمَا خَطۡبُكُمۡ أَيُّهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ
Ó sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”
Surah Al-Hijr, Verse 57
قَالُوٓاْ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمٖ مُّجۡرِمِينَ
Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni
Surah Al-Hijr, Verse 58
إِلَّآ ءَالَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمۡ أَجۡمَعِينَ
Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá
Surah Al-Hijr, Verse 59
إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ قَدَّرۡنَآ إِنَّهَا لَمِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ
Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun
Surah Al-Hijr, Verse 60
فَلَمَّا جَآءَ ءَالَ لُوطٍ ٱلۡمُرۡسَلُونَ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt
Surah Al-Hijr, Verse 61
قَالَ إِنَّكُمۡ قَوۡمٞ مُّنكَرُونَ
(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”
Surah Al-Hijr, Verse 62
قَالُواْ بَلۡ جِئۡنَٰكَ بِمَا كَانُواْ فِيهِ يَمۡتَرُونَ
Wọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 63
وَأَتَيۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ
A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa
Surah Al-Hijr, Verse 64
فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَٱتَّبِعۡ أَدۡبَٰرَهُمۡ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٞ وَٱمۡضُواْ حَيۡثُ تُؤۡمَرُونَ
Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fun yín
Surah Al-Hijr, Verse 65
وَقَضَيۡنَآ إِلَيۡهِ ذَٰلِكَ ٱلۡأَمۡرَ أَنَّ دَابِرَ هَـٰٓؤُلَآءِ مَقۡطُوعٞ مُّصۡبِحِينَ
A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́
Surah Al-Hijr, Verse 66
وَجَآءَ أَهۡلُ ٱلۡمَدِينَةِ يَسۡتَبۡشِرُونَ
Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 67
قَالَ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ ضَيۡفِي فَلَا تَفۡضَحُونِ
(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí
Surah Al-Hijr, Verse 68
وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ
Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi
Surah Al-Hijr, Verse 69
قَالُوٓاْ أَوَلَمۡ نَنۡهَكَ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”
Surah Al-Hijr, Verse 70
قَالَ هَـٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِيٓ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ
Ó sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”
Surah Al-Hijr, Verse 71
لَعَمۡرُكَ إِنَّهُمۡ لَفِي سَكۡرَتِهِمۡ يَعۡمَهُونَ
(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra; dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìdààmú ọpọlọ, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”
Surah Al-Hijr, Verse 72
فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ مُشۡرِقِينَ
Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn
Surah Al-Hijr, Verse 73
فَجَعَلۡنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةٗ مِّن سِجِّيلٍ
A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí
Surah Al-Hijr, Verse 74
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُتَوَسِّمِينَ
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye
Surah Al-Hijr, Verse 75
وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٖ مُّقِيمٍ
Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀)
Surah Al-Hijr, Verse 76
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Al-Hijr, Verse 77
وَإِن كَانَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأَيۡكَةِ لَظَٰلِمِينَ
Àwọn ará ’Aekah náà jẹ́ alábòsí
Surah Al-Hijr, Verse 78
فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٖ مُّبِينٖ
A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì l’ó kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀)
Surah Al-Hijr, Verse 79
وَلَقَدۡ كَذَّبَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡحِجۡرِ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́
Surah Al-Hijr, Verse 80
وَءَاتَيۡنَٰهُمۡ ءَايَٰتِنَا فَكَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ
A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀
Surah Al-Hijr, Verse 81
وَكَانُواْ يَنۡحِتُونَ مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتًا ءَامِنِينَ
Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta
Surah Al-Hijr, Verse 82
فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ مُصۡبِحِينَ
Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́
Surah Al-Hijr, Verse 83
فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà)
Surah Al-Hijr, Verse 84
وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَإِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةٞۖ فَٱصۡفَحِ ٱلصَّفۡحَ ٱلۡجَمِيلَ
A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò t’ó rẹwà
Surah Al-Hijr, Verse 85
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلۡخَلَّـٰقُ ٱلۡعَلِيمُ
Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 86
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَٰكَ سَبۡعٗا مِّنَ ٱلۡمَثَانِي وَٱلۡقُرۡءَانَ ٱلۡعَظِيمَ
Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān t’ó tóbi
Surah Al-Hijr, Verse 87
لَا تَمُدَّنَّ عَيۡنَيۡكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّنۡهُمۡ وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَٱخۡفِضۡ جَنَاحَكَ لِلۡمُؤۡمِنِينَ
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé lóríṣiríṣi fún àwọn kan nínú wọn. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Al-Hijr, Verse 88
وَقُلۡ إِنِّيٓ أَنَا ٱلنَّذِيرُ ٱلۡمُبِينُ
Kí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
Surah Al-Hijr, Verse 89
كَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَى ٱلۡمُقۡتَسِمِينَ
Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn t’ó ń pín òdodo mọ́ irọ́
Surah Al-Hijr, Verse 90
ٱلَّذِينَ جَعَلُواْ ٱلۡقُرۡءَانَ عِضِينَ
àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín
Surah Al-Hijr, Verse 91
فَوَرَبِّكَ لَنَسۡـَٔلَنَّهُمۡ أَجۡمَعِينَ
Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè
Surah Al-Hijr, Verse 92
عَمَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Al-Hijr, Verse 93
فَٱصۡدَعۡ بِمَا تُؤۡمَرُ وَأَعۡرِضۡ عَنِ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah Al-Hijr, Verse 94
إِنَّا كَفَيۡنَٰكَ ٱلۡمُسۡتَهۡزِءِينَ
Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́
Surah Al-Hijr, Verse 95
ٱلَّذِينَ يَجۡعَلُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
àwọn t’ó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀
Surah Al-Hijr, Verse 96
وَلَقَدۡ نَعۡلَمُ أَنَّكَ يَضِيقُ صَدۡرُكَ بِمَا يَقُولُونَ
Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ
Surah Al-Hijr, Verse 97
فَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ وَكُن مِّنَ ٱلسَّـٰجِدِينَ
Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ. Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un)
Surah Al-Hijr, Verse 98
وَٱعۡبُدۡ رَبَّكَ حَتَّىٰ يَأۡتِيَكَ ٱلۡيَقِينُ
Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ
Surah Al-Hijr, Verse 99