Surah An-Nahl - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
أَتَىٰٓ أَمۡرُ ٱللَّهِ فَلَا تَسۡتَعۡجِلُوهُۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I
Surah An-Nahl, Verse 1
يُنَزِّلُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ بِٱلرُّوحِ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرُوٓاْ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱتَّقُونِ
(Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”
Surah An-Nahl, Verse 2
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ تَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I
Surah An-Nahl, Verse 3
خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ
Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde)
Surah An-Nahl, Verse 4
وَٱلۡأَنۡعَٰمَ خَلَقَهَاۖ لَكُمۡ فِيهَا دِفۡءٞ وَمَنَٰفِعُ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn. Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fun yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn
Surah An-Nahl, Verse 5
وَلَكُمۡ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسۡرَحُونَ
Ọ̀ṣọ́ tún ń bẹ fun yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko
Surah An-Nahl, Verse 6
وَتَحۡمِلُ أَثۡقَالَكُمۡ إِلَىٰ بَلَدٖ لَّمۡ تَكُونُواْ بَٰلِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ ٱلۡأَنفُسِۚ إِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ
Wọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín t’ó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ ò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́
Surah An-Nahl, Verse 7
وَٱلۡخَيۡلَ وَٱلۡبِغَالَ وَٱلۡحَمِيرَ لِتَرۡكَبُوهَا وَزِينَةٗۚ وَيَخۡلُقُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
(Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ ò mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 8
وَعَلَى ٱللَّهِ قَصۡدُ ٱلسَّبِيلِ وَمِنۡهَا جَآئِرٞۚ وَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ
Allāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀) . Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām)
Surah An-Nahl, Verse 9
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗۖ لَّكُم مِّنۡهُ شَرَابٞ وَمِنۡهُ شَجَرٞ فِيهِ تُسِيمُونَ
Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Mímu wà fun yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀. Ẹ sì ń fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn
Surah An-Nahl, Verse 10
يُنۢبِتُ لَكُم بِهِ ٱلزَّرۡعَ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلنَّخِيلَ وَٱلۡأَعۡنَٰبَ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
(Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fun yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀
Surah An-Nahl, Verse 11
وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتُۢ بِأَمۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fun yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè
Surah An-Nahl, Verse 12
وَمَا ذَرَأَ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَذَّكَّرُونَ
Àti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fun yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń lo ìrántí
Surah An-Nahl, Verse 13
وَهُوَ ٱلَّذِي سَخَّرَ ٱلۡبَحۡرَ لِتَأۡكُلُواْ مِنۡهُ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُواْ مِنۡهُ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Òun ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - ó sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ – àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn àjùlọ oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu)
Surah An-Nahl, Verse 14
وَأَلۡقَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمۡ وَأَنۡهَٰرٗا وَسُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ
Ó sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 15
وَعَلَٰمَٰتٖۚ وَبِٱلنَّجۡمِ هُمۡ يَهۡتَدُونَ
àti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́)
Surah An-Nahl, Verse 16
أَفَمَن يَخۡلُقُ كَمَن لَّا يَخۡلُقُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni
Surah An-Nahl, Verse 17
وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ
Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́
Surah An-Nahl, Verse 18
وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعۡلِنُونَ
Àti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀
Surah An-Nahl, Verse 19
وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ
Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn
Surah An-Nahl, Verse 20
أَمۡوَٰتٌ غَيۡرُ أَحۡيَآءٖۖ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ
Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè. Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò gbé wọn dìde. wọn kì í ṣe alààyè.” kò sọ ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ohun t’ó ti ṣẹlẹ̀. Ṣebí àwọn mọlāika kan wà lára n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣé òkú ni àwọn mọlaika náà ni tàbí alààyè? A ò kúkú tí ì gbọ́ ikú mọlaika kan kan rí. Bákan náà aṣ-Ṣatọ̄n ar-Rọjīm jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún. Ṣé òkú ni Ṣaetọ̄n náà ni tàbí alààyè? Rárá bí Allāhu ṣe fẹ́.” Kò wá sí ẹ̀rí tààrà kan kan t’ó fi rinlẹ̀ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú bí kò ṣe āyah onípọ́nna èyí tí a ti ṣe àlàyé lórí rẹ̀ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n 3:55. Dípò kí á rí āyah kan tàbí hadīth kan tààrà lórí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) hadīth t’ó ń fi ìpadàbọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ l’à ń rí. Ẹni tí kò ì kú l’ó sì lè padà wá sílé ayé. ” nínú āyah náà kì í ṣe ìtúmọ̀ àdámọ́. Ìdí ni pé ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀
Surah An-Nahl, Verse 21
إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۚ فَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٞ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ
Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga
Surah An-Nahl, Verse 22
لَا جَرَمَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡتَكۡبِرِينَ
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga
Surah An-Nahl, Verse 23
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡ قَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”
Surah An-Nahl, Verse 24
لِيَحۡمِلُوٓاْ أَوۡزَارَهُمۡ كَامِلَةٗ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَمِنۡ أَوۡزَارِ ٱلَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۗ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ
(Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú
Surah An-Nahl, Verse 25
قَدۡ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَى ٱللَّهُ بُنۡيَٰنَهُم مِّنَ ٱلۡقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّقۡفُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó láti ìpìlẹ̀. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura
Surah An-Nahl, Verse 26
ثُمَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُخۡزِيهِمۡ وَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تُشَـٰٓقُّونَ فِيهِمۡۚ قَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ إِنَّ ٱلۡخِزۡيَ ٱلۡيَوۡمَ وَٱلسُّوٓءَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde (Allāhu) yóò yẹpẹrẹ wọn. Ó sì máa sọ pé: “Ibo ni àwọn (tí ẹ sọ di) akẹgbẹ́ Mi wà, àwọn tí ẹ tì torí wọn yapa (Mi)?” Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ẹ̀sìn yó sì sọ pé: “Dájúdájú àbùkù àti aburú ọjọ́ òní wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
Surah An-Nahl, Verse 27
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡۖ فَأَلۡقَوُاْ ٱلسَّلَمَ مَا كُنَّا نَعۡمَلُ مِن سُوٓءِۭۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
(Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Rárá (ẹ ṣiṣẹ́ aburú)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah An-Nahl, Verse 28
فَٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَلَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ
Nítorí náà, ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà Iná lọ, olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú
Surah An-Nahl, Verse 29
۞وَقِيلَ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ مَاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡۚ قَالُواْ خَيۡرٗاۗ لِّلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۚ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞۚ وَلَنِعۡمَ دَارُ ٱلۡمُتَّقِينَ
Wọ́n sọ fún àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Rere ni.” Rere ti wà fún àwọn t’ó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn lóore jùlọ. Àti pé dájúdájú ilé àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) dára
Surah An-Nahl, Verse 30
جَنَّـٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ لَهُمۡ فِيهَا مَا يَشَآءُونَۚ كَذَٰلِكَ يَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلۡمُتَّقِينَ
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)
Surah An-Nahl, Verse 31
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمُ ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Àwọn tí mọlāika ń pa, nígbà tí wọ́n ń ṣe rere lọ́wọ́, (àwọn mọlāika) ń sọ pé: “Àlàáfíà fun yín. Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Surah An-Nahl, Verse 32
هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ أَوۡ يَأۡتِيَ أَمۡرُ رَبِّكَۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ
Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí
Surah An-Nahl, Verse 33
فَأَصَابَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Nítorí náà, àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po
Surah An-Nahl, Verse 34
وَقَالَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا عَبَدۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖ نَّحۡنُ وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ فَهَلۡ عَلَى ٱلرُّسُلِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Àwọn tí wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́ yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fẹ́ ni àwa ìbá tí jọ́sìn fún kiní kan lẹ́yìn Rẹ̀, àwa àti àwọn bàbá wa. Bákàn náà, àwa ìbá tí ṣe kiní kan ní èèwọ̀ lẹ́yìn Rẹ̀.” Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ti ṣe. Ǹjẹ́ ojúṣe kan wà fún àwọn Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé
Surah An-Nahl, Verse 35
وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّـٰغُوتَۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ هَدَى ٱللَّهُ وَمِنۡهُم مَّنۡ حَقَّتۡ عَلَيۡهِ ٱلضَّلَٰلَةُۚ فَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ
Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn t’ó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí
Surah An-Nahl, Verse 36
إِن تَحۡرِصۡ عَلَىٰ هُدَىٰهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَن يُضِلُّۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Tí o bá ń ṣojú kòkòrò sí ìmọ̀nà wọn, ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, dájúdájú kò níí fi mọ̀nà, kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan kan fún wọn
Surah An-Nahl, Verse 37
وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَا يَبۡعَثُ ٱللَّهُ مَن يَمُوتُۚ بَلَىٰ وَعۡدًا عَلَيۡهِ حَقّٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Allāhu kò níí gbé ẹni tí ó kú dìde.” Kò rí bẹ́ẹ̀, (àjíǹde jẹ́) àdéhùn lọ́dọ̀ Allāhu. Òdodo sì ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 38
لِيُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي يَخۡتَلِفُونَ فِيهِ وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰذِبِينَ
(Allāhu yóò gbé ẹ̀dá dìde) nítorí kí Ó lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí fún wọn àti nítorí kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lè mọ̀ pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ òpùrọ́
Surah An-Nahl, Verse 39
إِنَّمَا قَوۡلُنَا لِشَيۡءٍ إِذَآ أَرَدۡنَٰهُ أَن نَّقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Ọ̀rọ̀ Wa fún kiní kan nígbà tí A bá gbèrò rẹ̀ ni pé, A máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
Surah An-Nahl, Verse 40
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا ظُلِمُواْ لَنُبَوِّئَنَّهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ti Allāhu, lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti ṣàbòsí sí wọn, dájúdájú Àwa yóò wá ibùgbé rere fún wọn. Ẹ̀san Ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé (àwọn tí kò ṣe hijrah) mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 41
ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
(Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù, wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn
Surah An-Nahl, Verse 42
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِمۡۖ فَسۡـَٔلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلذِّكۡرِ إِن كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀. kì í ṣe àwọn sūfī. Ìdí ni pé okùnfà āyah méjèèjì yìí ni pé
Surah An-Nahl, Verse 43
بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِۗ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلذِّكۡرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيۡهِمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ
(A fi) àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀
Surah An-Nahl, Verse 44
أَفَأَمِنَ ٱلَّذِينَ مَكَرُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَخۡسِفَ ٱللَّهُ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Ṣé àwọn t’ó dá ète aburú fi ọkàn balẹ̀ pé Allāhu kò lè mú ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ni, tàbí pé ìyà kò lè dé bá wọn láti àyè tí wọn kò ti níí fura
Surah An-Nahl, Verse 45
أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ فِي تَقَلُّبِهِمۡ فَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ
Tàbí (Allāhu) kò lè gbá wọn mú lórí ìrìnkè-rindò wọn ni? Wọn kò sì níí mórí bọ́
Surah An-Nahl, Verse 46
أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ عَلَىٰ تَخَوُّفٖ فَإِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٌ
Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú díẹ̀díẹ̀ ni? Nítorí náà, dájúdájú Olúwa yin má ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́
Surah An-Nahl, Verse 47
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ يَتَفَيَّؤُاْ ظِلَٰلُهُۥ عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَٱلشَّمَآئِلِ سُجَّدٗا لِّلَّهِ وَهُمۡ دَٰخِرُونَ
Àti pé ṣé wọn kò rí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń padà yọ láti ọ̀tún àti òsì ní olùforíkanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)
Surah An-Nahl, Verse 48
وَلِلَّهِۤ يَسۡجُدُۤ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن دَآبَّةٖ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ
Allāhu sì ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ní n̄ǹkan abẹ̀mí àti àwọn mọlāika ń forí kanlẹ̀ fún. Wọn kò sì ṣègbéraga
Surah An-Nahl, Verse 49
يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ۩
Wọ́n ń páyà Olúwa wọn t’Ó ń bẹ lókè wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn
Surah An-Nahl, Verse 50
۞وَقَالَ ٱللَّهُ لَا تَتَّخِذُوٓاْ إِلَٰهَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِۖ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَإِيَّـٰيَ فَٱرۡهَبُونِ
Allāhu sọ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ọlọ́hun méjì. Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Nítorí náà, Èmi (nìkan) ni kí ẹ bẹ̀rù.”
Surah An-Nahl, Verse 51
وَلَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَهُ ٱلدِّينُ وَاصِبًاۚ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَتَّقُونَ
TiRẹ̀ sì ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. TiRẹ̀ sì ni ẹ̀sìn títí láéláé Nítorí náà, ṣé (n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí Allāhu ni ẹ̀yin yóò máa bẹ̀rù ni
Surah An-Nahl, Verse 52
وَمَا بِكُم مِّن نِّعۡمَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ ٱلضُّرُّ فَإِلَيۡهِ تَجۡـَٔرُونَ
Ohunkóhun tí ẹ ní nínú ìdẹ̀ra, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Lẹ́yìn náà, tí ọwọ́ ìnira bá tẹ̀ yín, Òun ni kí ẹ máa pè (fún ìdáǹdè)
Surah An-Nahl, Verse 53
ثُمَّ إِذَا كَشَفَ ٱلضُّرَّ عَنكُمۡ إِذَا فَرِيقٞ مِّنكُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá sì mú ìnira náà kúrò fun yín tán, nígbà náà ni apá kan nínú yín yó sì máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
Surah An-Nahl, Verse 54
لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn. Nítorí náà, ẹ máa gbádùn ǹsó. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 55
وَيَجۡعَلُونَ لِمَا لَا يَعۡلَمُونَ نَصِيبٗا مِّمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡۗ تَٱللَّهِ لَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَفۡتَرُونَ
Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò mọ̀. Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́
Surah An-Nahl, Verse 56
وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ ٱلۡبَنَٰتِ سُبۡحَٰنَهُۥ وَلَهُم مَّا يَشۡتَهُونَ
Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). – Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn
Surah An-Nahl, Verse 57
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِٱلۡأُنثَىٰ ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٞ
Nígbà tí wọ́n bá fún ọ̀kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú (pé ó bí) ọmọbìnrin, ojú rẹ̀ yóò ṣókùnkùn, ó sì máa kún fún ìbànújẹ́
Surah An-Nahl, Verse 58
يَتَوَٰرَىٰ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ مِن سُوٓءِ مَا بُشِّرَ بِهِۦٓۚ أَيُمۡسِكُهُۥ عَلَىٰ هُونٍ أَمۡ يَدُسُّهُۥ فِي ٱلتُّرَابِۗ أَلَا سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ
Ó sì máa fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ìró aburú tí wọ́n fún un. Ṣé ó máa gbà á ní n̄ǹkan àbùkù ni tàbí ó máa bò ó mọ́lẹ̀ láàyè? Ẹ gbọ́, ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú
Surah An-Nahl, Verse 59
لِلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ مَثَلُ ٱلسَّوۡءِۖ وَلِلَّهِ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ni àkàwé aburú. Ti Allāhu sì ni àkàwé t’ó ga jùlọ. Àti pé Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah An-Nahl, Verse 60
وَلَوۡ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِظُلۡمِهِم مَّا تَرَكَ عَلَيۡهَا مِن دَآبَّةٖ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ لَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ سَاعَةٗ وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń gbá àwọn ènìyàn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn, ìbá tí ṣẹ́ abẹ̀mí kan kan kù sórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú di ìgbà kan, wọn kò sì níí fà á sẹ́yìn.”
Surah An-Nahl, Verse 61
وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ مَا يَكۡرَهُونَۚ وَتَصِفُ أَلۡسِنَتُهُمُ ٱلۡكَذِبَ أَنَّ لَهُمُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ لَا جَرَمَ أَنَّ لَهُمُ ٱلنَّارَ وَأَنَّهُم مُّفۡرَطُونَ
Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) n̄ǹkan tí wọn kórira lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni
Surah An-Nahl, Verse 62
تَٱللَّهِ لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَهُوَ وَلِيُّهُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Mo fi Allāhu búra, dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn lónìí. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn
Surah An-Nahl, Verse 63
وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا لِتُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí; ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo
Surah An-Nahl, Verse 64
وَٱللَّهُ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ
Allāhu l’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì ń fi jí ilẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀ (òdodo)
Surah An-Nahl, Verse 65
وَإِنَّ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَنۡعَٰمِ لَعِبۡرَةٗۖ نُّسۡقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِۦ مِنۢ بَيۡنِ فَرۡثٖ وَدَمٖ لَّبَنًا خَالِصٗا سَآئِغٗا لِّلشَّـٰرِبِينَ
Dájúdájú àríwòye wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fun yín mu nínú n̄ǹkan t’ó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ t’ó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn t’ó ń mu ún
Surah An-Nahl, Verse 66
وَمِن ثَمَرَٰتِ ٱلنَّخِيلِ وَٱلۡأَعۡنَٰبِ تَتَّخِذُونَ مِنۡهُ سَكَرٗا وَرِزۡقًا حَسَنًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
Àti pé láti ara àwọn èso dàbínù àti èso àjàrà ni ẹ ti ń ṣe ọtí àti ohun àmú-ṣọrọ̀ t’ó dára. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè
Surah An-Nahl, Verse 67
وَأَوۡحَىٰ رَبُّكَ إِلَى ٱلنَّحۡلِ أَنِ ٱتَّخِذِي مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتٗا وَمِنَ ٱلشَّجَرِ وَمِمَّا يَعۡرِشُونَ
Olúwa rẹ sì fi mọ kòkòrò oyin pé: "Mu ilé sínú àpáta, igi àti ohun tí (àwọn ènìyàn) mọ ga
Surah An-Nahl, Verse 68
ثُمَّ كُلِي مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ فَٱسۡلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلٗاۚ يَخۡرُجُ مِنۢ بُطُونِهَا شَرَابٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ فِيهِ شِفَآءٞ لِّلنَّاسِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
Lẹ́yìn náà, jẹ lára gbogbo èso, kí o sì tọ àwọn ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ìtẹríba." Ohun mímu tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn yóò máa jáde láti inú kòkòrò oyin. Ìwòsàn ni fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀
Surah An-Nahl, Verse 69
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ ثُمَّ يَتَوَفَّىٰكُمۡۚ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡ لَا يَعۡلَمَ بَعۡدَ عِلۡمٖ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٞ قَدِيرٞ
Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá yín. Lẹ́yìn náà, Ó ń gba ẹ̀mí yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá padà sí ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alágbára
Surah An-Nahl, Verse 70
وَٱللَّهُ فَضَّلَ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلرِّزۡقِۚ فَمَا ٱلَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزۡقِهِمۡ عَلَىٰ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَهُمۡ فِيهِ سَوَآءٌۚ أَفَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ
Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, kí wọ́n fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, kí wọ́n sì jọ pín in ní dọ́gbadọ́gba! Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò
Surah An-Nahl, Verse 71
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُم بَنِينَ وَحَفَدَةٗ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ أَفَبِٱلۡبَٰطِلِ يُؤۡمِنُونَ وَبِنِعۡمَتِ ٱللَّهِ هُمۡ يَكۡفُرُونَ
Àti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fun yín láti ara yín. Ó fun yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, wọn yó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ìdẹ̀ra Allāhu
Surah An-Nahl, Verse 72
وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَمۡلِكُ لَهُمۡ رِزۡقٗا مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ شَيۡـٔٗا وَلَا يَسۡتَطِيعُونَ
Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan)
Surah An-Nahl, Verse 73
فَلَا تَضۡرِبُواْ لِلَّهِ ٱلۡأَمۡثَالَۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn àkàwé náà lélẹ̀ nípa Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀
Surah An-Nahl, Verse 74
۞ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا عَبۡدٗا مَّمۡلُوكٗا لَّا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَمَن رَّزَقۡنَٰهُ مِنَّا رِزۡقًا حَسَنٗا فَهُوَ يُنفِقُ مِنۡهُ سِرّٗا وَجَهۡرًاۖ هَلۡ يَسۡتَوُۥنَۚ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí t’ó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 75
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا رَّجُلَيۡنِ أَحَدُهُمَآ أَبۡكَمُ لَا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَهُوَ كَلٌّ عَلَىٰ مَوۡلَىٰهُ أَيۡنَمَا يُوَجِّههُّ لَا يَأۡتِ بِخَيۡرٍ هَلۡ يَسۡتَوِي هُوَ وَمَن يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَهُوَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Allāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà
Surah An-Nahl, Verse 76
وَلِلَّهِ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَآ أَمۡرُ ٱلسَّاعَةِ إِلَّا كَلَمۡحِ ٱلۡبَصَرِ أَوۡ هُوَ أَقۡرَبُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀rọ̀ Àkókò náà kò kúkú tayọ ìṣẹ́jú tàbí kí ó tún súnmọ́ julọ. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah An-Nahl, Verse 77
وَٱللَّهُ أَخۡرَجَكُم مِّنۢ بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ شَيۡـٔٗا وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفۡـِٔدَةَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)
Surah An-Nahl, Verse 78
أَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَى ٱلطَّيۡرِ مُسَخَّرَٰتٖ فِي جَوِّ ٱلسَّمَآءِ مَا يُمۡسِكُهُنَّ إِلَّا ٱللَّهُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé wọn kò wòye sí àwọn ẹyẹ tí A rọ̀ (fún fífò) nínú òfurufú (lábẹ́) sánmọ̀? Kò sí ẹni t’ó ń mú wọn dúró (sínú òfurufú) bí kò ṣe Allāhu. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo
Surah An-Nahl, Verse 79
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمۡ سَكَنٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ بُيُوتٗا تَسۡتَخِفُّونَهَا يَوۡمَ ظَعۡنِكُمۡ وَيَوۡمَ إِقَامَتِكُمۡ وَمِنۡ أَصۡوَافِهَا وَأَوۡبَارِهَا وَأَشۡعَارِهَآ أَثَٰثٗا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ
Allāhu ṣe ibùsinmi fun yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan t’ó fúyẹ́ fun yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn, irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀. aṣọ èyí tí wọ́n bá fi irun àgùtàn hún máa ń jẹ́ aṣọ t’ó rọjú jùlọ ní rírà. Nítorí èyí aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ àwọn mẹ̀kúnnù. Àwọn olówó kì í sì fẹ́ rà á fún wíwọ̀ sọ́rùn nítorí pé olùfọkànsìn ẹni ẹ̀ṣà òǹpèrò kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àáfà onibidiah wọ̀nyẹn bá tún bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara rẹ̀ pèrò dípò lílo orúkọ àgbélẹ̀rọ tí wọ́n dìjọ ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni ayé wọn bá di ìlànà / tọrīkọ “at-tasọwuffu al-kọ̄diriyyah” tí ọkùnrin kan kò bá ti rí iṣẹ́ halāl ṣe ní iṣẹ́ òòjọ́ ó máa di “ṣééù”
Surah An-Nahl, Verse 80
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَٰلٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡجِبَالِ أَكۡنَٰنٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ سَرَٰبِيلَ تَقِيكُمُ ٱلۡحَرَّ وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأۡسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُسۡلِمُونَ
Allāhu ṣe àwọn ibòji fun yín láti ara n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fun yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fun yín t’ó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ t’ó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín. Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí
Surah An-Nahl, Verse 81
فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé lojúṣe tìrẹ
Surah An-Nahl, Verse 82
يَعۡرِفُونَ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Wọ́n mọ ìdẹ̀ra Allāhu, lẹ́yìn náà wọ́n ń takò ó. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni aláìmoore
Surah An-Nahl, Verse 83
وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ مِن كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدٗا ثُمَّ لَا يُؤۡذَنُ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ
(Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu
Surah An-Nahl, Verse 84
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلۡعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ
Nígbà tí àwọn t’ó ṣàbòsí bá rí Ìyà, nígbà náà, A ò níí ṣe ìyà wọn ní fífúyẹ́, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná)
Surah An-Nahl, Verse 85
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ شُرَكَآءَهُمۡ قَالُواْ رَبَّنَا هَـٰٓؤُلَآءِ شُرَكَآؤُنَا ٱلَّذِينَ كُنَّا نَدۡعُواْ مِن دُونِكَۖ فَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلَ إِنَّكُمۡ لَكَٰذِبُونَ
Nígbà tí àwọn t’ó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ bá rí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni àwọn òrìṣà wa tí à ń pè lẹ́yìn Rẹ.” Nígbà náà (àwọn òrìṣà) yóò ju ọ̀rọ̀ náà padà sí wọ́n pé: “Dájúdájú òpùrọ́ mà ni ẹ̀yin.”
Surah An-Nahl, Verse 86
وَأَلۡقَوۡاْ إِلَى ٱللَّهِ يَوۡمَئِذٍ ٱلسَّلَمَۖ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Wọ́n sì máa jura wọn sílẹ̀ fún Allāhu ní ọjọ́ yẹn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ yó sì di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́
Surah An-Nahl, Verse 87
ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ زِدۡنَٰهُمۡ عَذَابٗا فَوۡقَ ٱلۡعَذَابِ بِمَا كَانُواْ يُفۡسِدُونَ
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́
Surah An-Nahl, Verse 88
وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ فِي كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدًا عَلَيۡهِم مِّنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَجِئۡنَا بِكَ شَهِيدًا عَلَىٰ هَـٰٓؤُلَآءِۚ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ تِبۡيَٰنٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُسۡلِمِينَ
(Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan, ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí
Surah An-Nahl, Verse 89
۞إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَٱلۡإِحۡسَٰنِ وَإِيتَآيِٕ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَيَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِ وَٱلۡبَغۡيِۚ يَعِظُكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ
Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí
Surah An-Nahl, Verse 90
وَأَوۡفُواْ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ إِذَا عَٰهَدتُّمۡ وَلَا تَنقُضُواْ ٱلۡأَيۡمَٰنَ بَعۡدَ تَوۡكِيدِهَا وَقَدۡ جَعَلۡتُمُ ٱللَّهَ عَلَيۡكُمۡ كَفِيلًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا تَفۡعَلُونَ
Kí ẹ sì mú àdéhùn Allāhu ṣẹ nígbà tí ẹ bá ṣe àdéhùn. Ẹ má ṣe tú ìbúra lẹ́yìn ìfirinlẹ̀ rẹ̀. Ẹ sì kúkú ti fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí lórí ara yín. Dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah An-Nahl, Verse 91
وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّتِي نَقَضَتۡ غَزۡلَهَا مِنۢ بَعۡدِ قُوَّةٍ أَنكَٰثٗا تَتَّخِذُونَ أَيۡمَٰنَكُمۡ دَخَلَۢا بَيۡنَكُمۡ أَن تَكُونَ أُمَّةٌ هِيَ أَرۡبَىٰ مِنۡ أُمَّةٍۚ إِنَّمَا يَبۡلُوكُمُ ٱللَّهُ بِهِۦۚ وَلَيُبَيِّنَنَّ لَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
Kí ẹ sì má ṣe dà bí (obìnrin) èyí tí ó tú òwú dídì rẹ̀ palẹ̀ lẹ́yìn tí ó tí dì í le. Ńṣe ni ẹ̀ ń lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín nítorí pé ìran kan pọ̀ ju ìran kan lọ. Dájúdájú Allāhu ń dan yín wò pẹ̀lú rẹ̀ ni. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde Ó kúkú máa ṣàlàyé fun yín ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí
Surah An-Nahl, Verse 92
وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَلَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n Ó ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Dájúdájú Wọ́n máa bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah An-Nahl, Verse 93
وَلَا تَتَّخِذُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡ دَخَلَۢا بَيۡنَكُمۡ فَتَزِلَّ قَدَمُۢ بَعۡدَ ثُبُوتِهَا وَتَذُوقُواْ ٱلسُّوٓءَ بِمَا صَدَدتُّمۡ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَكُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Ẹ má ṣe lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín, nítorí kí ẹsẹ̀ yín má baà yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìdúróṣinṣin rẹ̀, àti nítorí kí ẹ má baà tọ́ ìyà burúkú wò nípa bí ẹ ṣe ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Ìyà ńlá yó sì wà fun yín
Surah An-Nahl, Verse 94
وَلَا تَشۡتَرُواْ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ ثَمَنٗا قَلِيلًاۚ إِنَّمَا عِندَ ٱللَّهِ هُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Ẹ má ṣe ta àdéhùn Allāhu ní owó pọ́ọ́kú. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu, ó lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀
Surah An-Nahl, Verse 95
مَا عِندَكُمۡ يَنفَدُ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ بَاقٖۗ وَلَنَجۡزِيَنَّ ٱلَّذِينَ صَبَرُوٓاْ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san àwọn t’ó ṣe sùúrù lẹ́san wọn
Surah An-Nahl, Verse 96
مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t’ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn
Surah An-Nahl, Verse 97
فَإِذَا قَرَأۡتَ ٱلۡقُرۡءَانَ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ ٱلرَّجِيمِ
Nígbà tí o bá (fẹ́) ké al-Ƙur’ān, sá di Allāhu níbi (aburú) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀
Surah An-Nahl, Verse 98
إِنَّهُۥ لَيۡسَ لَهُۥ سُلۡطَٰنٌ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
Dájúdájú kò sí agbára kan fún un lórí àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn
Surah An-Nahl, Verse 99
إِنَّمَا سُلۡطَٰنُهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ يَتَوَلَّوۡنَهُۥ وَٱلَّذِينَ هُم بِهِۦ مُشۡرِكُونَ
Ẹni t’ó lágbára lórí rẹ̀ ni àwọn t’ó ń mú un ní ọ̀rẹ́ àti àwọn t’ó sọ ọ́ di akẹgbẹ́ Allāhu
Surah An-Nahl, Verse 100
وَإِذَا بَدَّلۡنَآ ءَايَةٗ مَّكَانَ ءَايَةٖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يُنَزِّلُ قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مُفۡتَرِۭۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Nígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun t’Ó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀
Surah An-Nahl, Verse 101
قُلۡ نَزَّلَهُۥ رُوحُ ٱلۡقُدُسِ مِن رَّبِّكَ بِٱلۡحَقِّ لِيُثَبِّتَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُسۡلِمِينَ
Sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní ti òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí
Surah An-Nahl, Verse 102
وَلَقَدۡ نَعۡلَمُ أَنَّهُمۡ يَقُولُونَ إِنَّمَا يُعَلِّمُهُۥ بَشَرٞۗ لِّسَانُ ٱلَّذِي يُلۡحِدُونَ إِلَيۡهِ أَعۡجَمِيّٞ وَهَٰذَا لِسَانٌ عَرَبِيّٞ مُّبِينٌ
A sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan l’ó ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń yẹ̀ sí (tí wọ́n ń tọ́ka sí pé ó ń kọ́ ọ) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí
Surah An-Nahl, Verse 103
إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَا يَهۡدِيهِمُ ٱللَّهُ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Dájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn
Surah An-Nahl, Verse 104
إِنَّمَا يَفۡتَرِي ٱلۡكَذِبَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ
Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu l’ó ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn sì ni òpùrọ́
Surah An-Nahl, Verse 105
مَن كَفَرَ بِٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ إِيمَٰنِهِۦٓ إِلَّا مَنۡ أُكۡرِهَ وَقَلۡبُهُۥ مُطۡمَئِنُّۢ بِٱلۡإِيمَٰنِ وَلَٰكِن مَّن شَرَحَ بِٱلۡكُفۡرِ صَدۡرٗا فَعَلَيۡهِمۡ غَضَبٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí àìgbàgbọ́ bá tẹ́ lọ́rùn, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn
Surah An-Nahl, Verse 106
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا عَلَى ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Ìyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́
Surah An-Nahl, Verse 107
أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَسَمۡعِهِمۡ وَأَبۡصَٰرِهِمۡۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni afọ́núfọ́ra
Surah An-Nahl, Verse 108
لَا جَرَمَ أَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run
Surah An-Nahl, Verse 109
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ هَاجَرُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا فُتِنُواْ ثُمَّ جَٰهَدُواْ وَصَبَرُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́)
Surah An-Nahl, Verse 110
۞يَوۡمَ تَأۡتِي كُلُّ نَفۡسٖ تُجَٰدِلُ عَن نَّفۡسِهَا وَتُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
(Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé láti du orí ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn
Surah An-Nahl, Verse 111
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا قَرۡيَةٗ كَانَتۡ ءَامِنَةٗ مُّطۡمَئِنَّةٗ يَأۡتِيهَا رِزۡقُهَا رَغَدٗا مِّن كُلِّ مَكَانٖ فَكَفَرَتۡ بِأَنۡعُمِ ٱللَّهِ فَأَذَٰقَهَا ٱللَّهُ لِبَاسَ ٱلۡجُوعِ وَٱلۡخَوۡفِ بِمَا كَانُواْ يَصۡنَعُونَ
Allāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah An-Nahl, Verse 112
وَلَقَدۡ جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡهُمۡ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَهُمۡ ظَٰلِمُونَ
Òjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n
Surah An-Nahl, Verse 113
فَكُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلٗا طَيِّبٗا وَٱشۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ
Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, t’ó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún
Surah An-Nahl, Verse 114
إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fun yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ t’ó yàtọ́ sí “Allāhu”. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fi ìnira ebi kan, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah An-Nahl, Verse 115
وَلَا تَقُولُواْ لِمَا تَصِفُ أَلۡسِنَتُكُمُ ٱلۡكَذِبَ هَٰذَا حَلَٰلٞ وَهَٰذَا حَرَامٞ لِّتَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ
Ẹ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè
Surah An-Nahl, Verse 116
مَتَٰعٞ قَلِيلٞ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Ìgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run)
Surah An-Nahl, Verse 117
وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا مَا قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُۖ وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ
Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn t’ó di yẹhudi. A ò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn
Surah An-Nahl, Verse 118
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٌ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn t’ó ṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe lẹ́yìn rẹ̀ dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah An-Nahl, Verse 119
إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ كَانَ أُمَّةٗ قَانِتٗا لِّلَّهِ حَنِيفٗا وَلَمۡ يَكُ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah An-Nahl, Verse 120
شَاكِرٗا لِّأَنۡعُمِهِۚ ٱجۡتَبَىٰهُ وَهَدَىٰهُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Ó máa ń dúpẹ́ àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Allāhu ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà (’Islām)
Surah An-Nahl, Verse 121
وَءَاتَيۡنَٰهُ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ
A ṣe ohun rere fún un nílé ayé. Àti pé ní ọ̀run dájúdájú ó máa wà nínú àwọn ẹni rere
Surah An-Nahl, Verse 122
ثُمَّ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ أَنِ ٱتَّبِعۡ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۖ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Lẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah An-Nahl, Verse 123
إِنَّمَا جُعِلَ ٱلسَّبۡتُ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِۚ وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ
Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn t’ó yapa ẹnu nípa rẹ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí
Surah An-Nahl, Verse 124
ٱدۡعُ إِلَىٰ سَبِيلِ رَبِّكَ بِٱلۡحِكۡمَةِ وَٱلۡمَوۡعِظَةِ ٱلۡحَسَنَةِۖ وَجَٰدِلۡهُم بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ
Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì s.a.w.) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí t’ó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí)
Surah An-Nahl, Verse 125
وَإِنۡ عَاقَبۡتُمۡ فَعَاقِبُواْ بِمِثۡلِ مَا عُوقِبۡتُم بِهِۦۖ وَلَئِن صَبَرۡتُمۡ لَهُوَ خَيۡرٞ لِّلصَّـٰبِرِينَ
Tí ẹ (bá fẹ́) gbẹ̀san (ìyà), ẹ gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣe sùúrù, ó mà sì lóore jùlọ fún àwọn onísùúrù
Surah An-Nahl, Verse 126
وَٱصۡبِرۡ وَمَا صَبۡرُكَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَلَا تَكُ فِي ضَيۡقٖ مِّمَّا يَمۡكُرُونَ
Ṣe sùúrù. Ìwọ kò sì lè rí sùúrù ṣe àfi pẹ̀lú (ìrànlọ́wọ́) Allāhu. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì ṣe wà nínú ìbànújẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń dá ní ète
Surah An-Nahl, Verse 127
إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّٱلَّذِينَ هُم مُّحۡسِنُونَ
Dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn t’ó ń ṣe rere
Surah An-Nahl, Verse 128