UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah An-Nahl - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


أَتَىٰٓ أَمۡرُ ٱللَّهِ فَلَا تَسۡتَعۡجِلُوهُۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

Ase Allahu de tan. E ma wule wa a pelu ikanju. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
Surah An-Nahl, Verse 1


يُنَزِّلُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ بِٱلرُّوحِ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ أَنۡ أَنذِرُوٓاْ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱتَّقُونِ

(Allahu) n fi ase Re so molaika (Jibril) kale lati maa mu imisi wa diedie fun enikeni ti O ba fe (bee fun) ninu awon erusin Re nitori ki e le fi se ikilo pe: “Dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, e beru Mi.”
Surah An-Nahl, Verse 2


خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ تَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
Surah An-Nahl, Verse 3


خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ

O da eniyan lati inu ato. (Eniyan) si di olujiyan ponnbele (nipa Ajinde)
Surah An-Nahl, Verse 4


وَٱلۡأَنۡعَٰمَ خَلَقَهَاۖ لَكُمۡ فِيهَا دِفۡءٞ وَمَنَٰفِعُ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ

Awon eran-osin, O seda won. Aso otutu ati awon anfaani (miiran) n be fun yin lara won. Ati pe e n je ninu won
Surah An-Nahl, Verse 5


وَلَكُمۡ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسۡرَحُونَ

Oso tun n be fun yin lara won nigba ti e ba n da won lo (si ile won) ati nigba ti e ba n ko won jade lo jeko
Surah An-Nahl, Verse 6


وَتَحۡمِلُ أَثۡقَالَكُمۡ إِلَىٰ بَلَدٖ لَّمۡ تَكُونُواْ بَٰلِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ ٱلۡأَنفُسِۚ إِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ

Won si n ru awon eru yin t’o wuwo lo si ilu kan ti e o le de afi pelu wahala emi. Dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee
Surah An-Nahl, Verse 7


وَٱلۡخَيۡلَ وَٱلۡبِغَالَ وَٱلۡحَمِيرَ لِتَرۡكَبُوهَا وَزِينَةٗۚ وَيَخۡلُقُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ

(O seda) esin, ibaaka ati ketekete nitori ki e le gun won. (Won tun je) oso. O tun n seda ohun ti e o mo
Surah An-Nahl, Verse 8


وَعَلَى ٱللَّهِ قَصۡدُ ٱلسَّبِيلِ وَمِنۡهَا جَآئِرٞۚ وَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ

Allahu l’O n salaye (’Islam) ona taara. Awon ona esin wiwo tun wa (loto) . Ti O ba fe bee ni, iba to gbogbo yin si ona (esin ’Islam)
Surah An-Nahl, Verse 9


هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗۖ لَّكُم مِّنۡهُ شَرَابٞ وَمِنۡهُ شَجَرٞ فِيهِ تُسِيمُونَ

Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. Mimu wa fun yin ninu re. Igi eweko tun n wu jade lati inu re. E si n fi bo awon eran-osin
Surah An-Nahl, Verse 10


يُنۢبِتُ لَكُم بِهِ ٱلزَّرۡعَ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلنَّخِيلَ وَٱلۡأَعۡنَٰبَ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ

(Allahu) tun n fi (omi yii) hu awon irugbin, igi ororo zaetun, igi dabinu, igi ajara ati gbogbo awon eso (yooku) jade fun yin. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
Surah An-Nahl, Verse 11


وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتُۢ بِأَمۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ

O ro oru, osan, oorun, osupa ati awon irawo fun yin pelu ase Re. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye
Surah An-Nahl, Verse 12


وَمَا ذَرَأَ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَذَّكَّرُونَ

Ati ohun ti O tun seda re fun yin lori ile, ti awon awo re je orisirisi. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n lo iranti
Surah An-Nahl, Verse 13


وَهُوَ ٱلَّذِي سَخَّرَ ٱلۡبَحۡرَ لِتَأۡكُلُواْ مِنۡهُ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُواْ مِنۡهُ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ

Oun ni Eni ti O ro agbami odo nitori ki e le je eran (eja) tutu ati nitori ki e le mu nnkan oso ti e oo maa wo sara jade lati inu (odo), - o si maa ri awon oko oju-omi ti yoo maa la oju omi koja lo bo – ati nitori ki e le wa ninu awon ajulo oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Allahu)
Surah An-Nahl, Verse 14


وَأَلۡقَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمۡ وَأَنۡهَٰرٗا وَسُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ

O si fi awon apata t’o duro gbagidi sori ile ki o ma fi le mi mo yin lese ati awon odo ati awon oju-ona nitori ki e le da oju ona mo
Surah An-Nahl, Verse 15


وَعَلَٰمَٰتٖۚ وَبِٱلنَّجۡمِ هُمۡ يَهۡتَدُونَ

ati awon ami opopona (fun itosona irin osan). Won tun n fi irawo da oju ona mo (lale)
Surah An-Nahl, Verse 16


أَفَمَن يَخۡلُقُ كَمَن لَّا يَخۡلُقُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Nje Eni ti O da eda da bi eni ti ko da eda bi? Nitori naa, se e o nii lo iranti ni
Surah An-Nahl, Verse 17


وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ

Ti e ba sonka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju Allahu ma ni Alaforijin, Onikee
Surah An-Nahl, Verse 18


وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعۡلِنُونَ

Ati pe Allahu mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n se afihan re
Surah An-Nahl, Verse 19


وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ

Awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu; won ko le da kini kan. Allahu l’O si seda won
Surah An-Nahl, Verse 20


أَمۡوَٰتٌ غَيۡرُ أَحۡيَآءٖۖ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ

Oku (ni won), won ki i se alaaye. Won ko si mo akoko ti A oo gbe won dide. won ki i se alaaye.” ko so iku Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) di ohun t’o ti sele. Sebi awon molaika kan wa lara nnkan ti awon eniyan n josin fun leyin Allahu. Se oku ni awon molaika naa ni tabi alaaye? A o kuku ti i gbo iku molaika kan kan ri. Bakan naa as-Saton ar-Rojim je okan pataki ninu ohun ti awon eniyan n josin fun. Se oku ni Saeton naa ni tabi alaaye? Rara bi Allahu se fe.” Ko wa si eri taara kan kan t’o fi rinle pe Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti ku bi ko se ayah oniponna eyi ti a ti se alaye lori re siwaju ninu itose-oro fun surah ali-’Imron 3:55. Dipo ki a ri ayah kan tabi hadith kan taara lori iku Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) hadith t’o n fi ipadabo re rinle l’a n ri. Eni ti ko i ku l’o si le pada wa sile aye. ” ninu ayah naa ki i se itumo adamo. Idi ni pe ere ti ko si emi lara re ni awon orisa naa. Ipo oku eni ti ko le soro
Surah An-Nahl, Verse 21


إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۚ فَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٞ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ

Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Amo awon ti ko ni igbagbo ninu Ojo Ikeyin ni okan won tako o, ti won si n segberaga
Surah An-Nahl, Verse 22


لَا جَرَمَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡتَكۡبِرِينَ

Ko si tabi-sugbon, dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re. Ati pe dajudaju (Allahu) ko nifee awon onigbeeraga
Surah An-Nahl, Verse 23


وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡ قَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ

Nigba ti won ba so fun won pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Akosile alo awon eni akoko ni.”
Surah An-Nahl, Verse 24


لِيَحۡمِلُوٓاْ أَوۡزَارَهُمۡ كَامِلَةٗ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَمِنۡ أَوۡزَارِ ٱلَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۗ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ

(Won so bee) nitori ki won le ru eru ese tiwon ni pipe perepere ni Ojo Ajinde ati (nitori ki won le ru) ninu eru ese awon ti won n si lona pelu ainimo. Gbo, ohun ti won yoo ru ni ese, o buru
Surah An-Nahl, Verse 25


قَدۡ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَى ٱللَّهُ بُنۡيَٰنَهُم مِّنَ ٱلۡقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّقۡفُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ

Awon t’o siwaju won kuku dete. Allahu si da ile won wo lati ipile. Orule si wo lu won mole lati oke won. Ati pe iya de ba won ni aye ti won ko ti fura
Surah An-Nahl, Verse 26


ثُمَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُخۡزِيهِمۡ وَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تُشَـٰٓقُّونَ فِيهِمۡۚ قَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ إِنَّ ٱلۡخِزۡيَ ٱلۡيَوۡمَ وَٱلسُّوٓءَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ

Leyin naa, ni Ojo Ajinde (Allahu) yoo yepere won. O si maa so pe: “Ibo ni awon (ti e so di) akegbe Mi wa, awon ti e ti tori won yapa (Mi)?” Awon ti A fun ni imo esin yo si so pe: “Dajudaju abuku ati aburu ojo oni wa fun awon alaigbagbo.”
Surah An-Nahl, Verse 27


ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡۖ فَأَلۡقَوُاْ ٱلسَّلَمَ مَا كُنَّا نَعۡمَلُ مِن سُوٓءِۭۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

(Awon ni) awon ti molaika n pa nigba ti won n sabosi si emi ara won lowo. Ni asiko yii ni won juwo juse sile (won si wi pe): “Awa ko se ise aburu kan kan.” Rara (e sise aburu)! Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti e n se nise
Surah An-Nahl, Verse 28


فَٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَلَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ

Nitori naa, e wo awon enu ona Ina lo, olusegbere ni yin ninu re. Ibugbe awon onigbeeraga si buru
Surah An-Nahl, Verse 29


۞وَقِيلَ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ مَاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡۚ قَالُواْ خَيۡرٗاۗ لِّلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۚ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞۚ وَلَنِعۡمَ دَارُ ٱلۡمُتَّقِينَ

Won so fun awon t’o beru (Allahu) pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Rere ni.” Rere ti wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Dajudaju Ile Ikeyin loore julo. Ati pe dajudaju ile awon oluberu (Allahu) dara
Surah An-Nahl, Verse 30


جَنَّـٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ لَهُمۡ فِيهَا مَا يَشَآءُونَۚ كَذَٰلِكَ يَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلۡمُتَّقِينَ

Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon odo yo si maa san ni isale re. Ohunkohun ti won ba n fe maa wa fun won ninu re. Bayen ni Allahu se n san esan rere fun awon oluberu (Re)
Surah An-Nahl, Verse 31


ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمُ ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

Awon ti molaika n pa, nigba ti won n se rere lowo, (awon molaika) n so pe: “Alaafia fun yin. E wo inu Ogba Idera nitori ohun ti e n se nise.”
Surah An-Nahl, Verse 32


هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ أَوۡ يَأۡتِيَ أَمۡرُ رَبِّكَۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ

Se won n reti ohun kan yato si pe ki awon molaika wa ba won tabi ki ase Oluwa re de? Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
Surah An-Nahl, Verse 33


فَأَصَابَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ

Nitori naa, awon aburu ohun ti won se nise sele si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po
Surah An-Nahl, Verse 34


وَقَالَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا عَبَدۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖ نَّحۡنُ وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ فَهَلۡ عَلَى ٱلرُّسُلِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ

Awon ti won ba Allahu wa akegbe yo si wi pe: “Ti o ba je pe Allahu fe ni awa iba ti josin fun kini kan leyin Re, awa ati awon baba wa. Bakan naa, awa iba ti se kini kan ni eewo leyin Re.” Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Nje ojuse kan wa fun awon Ojise bi ko se ise-jije ponnbele
Surah An-Nahl, Verse 35


وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّـٰغُوتَۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ هَدَى ٱللَّهُ وَمِنۡهُم مَّنۡ حَقَّتۡ عَلَيۡهِ ٱلضَّلَٰلَةُۚ فَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ

Dajudaju A ti gbe Ojise dide ninu ijo kookan (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. Ki e si jinna si awon orisa.” Nitori naa, o wa ninu won, eni ti Allahu to si ona. O si wa ninu won, eni ti isina ko le lori. Nitori naa, e rin kiri lori ile, ki e si woye si bi atubotan awon t’o pe awon Ojise ni opuro se ri
Surah An-Nahl, Verse 36


إِن تَحۡرِصۡ عَلَىٰ هُدَىٰهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَن يُضِلُّۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Ti o ba n soju kokoro si imona won, eni ti Allahu ba si lona, dajudaju ko nii fi mona, ko si nii si awon alaranse kan kan fun won
Surah An-Nahl, Verse 37


وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَا يَبۡعَثُ ٱللَّهُ مَن يَمُوتُۚ بَلَىٰ وَعۡدًا عَلَيۡهِ حَقّٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ

Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: “Allahu ko nii gbe eni ti o ku dide.” Ko ri bee, (ajinde je) adehun lodo Allahu. Ododo si ni, sugbon opolopo eniyan ko mo
Surah An-Nahl, Verse 38


لِيُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي يَخۡتَلِفُونَ فِيهِ وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰذِبِينَ

(Allahu yoo gbe eda dide) nitori ki O le salaye ohun ti won n yapa enu si fun won ati nitori ki awon t’o sai gbagbo le mo pe dajudaju awon ni won je opuro
Surah An-Nahl, Verse 39


إِنَّمَا قَوۡلُنَا لِشَيۡءٍ إِذَآ أَرَدۡنَٰهُ أَن نَّقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

Oro Wa fun kini kan nigba ti A ba gbero re ni pe, A maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee.”
Surah An-Nahl, Verse 40


وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا ظُلِمُواْ لَنُبَوِّئَنَّهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ

Awon t’o gbe ilu won ju sile nitori ti Allahu, leyin ti awon alaigbagbo ti sabosi si won, dajudaju Awa yoo wa ibugbe rere fun won. Esan Ojo Ikeyin si tobi julo, ti o ba je pe (awon ti ko se hijrah) mo
Surah An-Nahl, Verse 41


ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ

(Awon ni) awon t’o se suuru, won si n gbarale Oluwa won
Surah An-Nahl, Verse 42


وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِمۡۖ فَسۡـَٔلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلذِّكۡرِ إِن كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ

A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo. ki i se awon sufi. Idi ni pe okunfa ayah mejeeji yii ni pe
Surah An-Nahl, Verse 43


بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِۗ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلذِّكۡرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيۡهِمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ

(A fi) awon eri t’o yanju ati ipin-ipin Tira (ran won nise). Ati pe A so tira Iranti (iyen, al-Ƙur’an) kale fun o nitori ki o le salaye fun awon eniyan ohun ti A sokale fun won ati nitori ki won le ronu jinle
Surah An-Nahl, Verse 44


أَفَأَمِنَ ٱلَّذِينَ مَكَرُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَخۡسِفَ ٱللَّهُ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ

Se awon t’o da ete aburu fi okan bale pe Allahu ko le mu ile ri mo won lese ni, tabi pe iya ko le de ba won lati aye ti won ko ti nii fura
Surah An-Nahl, Verse 45


أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ فِي تَقَلُّبِهِمۡ فَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ

Tabi (Allahu) ko le gba won mu lori irinke-rindo won ni? Won ko si nii mori bo
Surah An-Nahl, Verse 46


أَوۡ يَأۡخُذَهُمۡ عَلَىٰ تَخَوُّفٖ فَإِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٌ

Tabi (Allahu) ko le maa gba won mu diedie ni? Nitori naa, dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee
Surah An-Nahl, Verse 47


أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ يَتَفَيَّؤُاْ ظِلَٰلُهُۥ عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَٱلشَّمَآئِلِ سُجَّدٗا لِّلَّهِ وَهُمۡ دَٰخِرُونَ

Ati pe se won ko ri gbogbo nnkan ti Allahu seda re, ti ooji re n pada yo lati otun ati osi ni oluforikanle fun Allahu; ti won si n yepere ara won (fun Un)
Surah An-Nahl, Verse 48


وَلِلَّهِۤ يَسۡجُدُۤ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن دَآبَّةٖ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ

Allahu si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni nnkan abemi ati awon molaika n fori kanle fun. Won ko si segberaga
Surah An-Nahl, Verse 49


يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ وَيَفۡعَلُونَ مَا يُؤۡمَرُونَ۩

Won n paya Oluwa won t’O n be loke won. Won si n se ohun ti A n pa lase fun won
Surah An-Nahl, Verse 50


۞وَقَالَ ٱللَّهُ لَا تَتَّخِذُوٓاْ إِلَٰهَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِۖ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَإِيَّـٰيَ فَٱرۡهَبُونِ

Allahu so pe: “E ma se josin fun olohun meji. Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Nitori naa, Emi (nikan) ni ki e beru.”
Surah An-Nahl, Verse 51


وَلَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَهُ ٱلدِّينُ وَاصِبًاۚ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَتَّقُونَ

TiRe si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. TiRe si ni esin titi laelae Nitori naa, se (nnkan miiran) yato si Allahu ni eyin yoo maa beru ni
Surah An-Nahl, Verse 52


وَمَا بِكُم مِّن نِّعۡمَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ ٱلضُّرُّ فَإِلَيۡهِ تَجۡـَٔرُونَ

Ohunkohun ti e ni ninu idera, lati odo Allahu ni. Leyin naa, ti owo inira ba te yin, Oun ni ki e maa pe (fun idande)
Surah An-Nahl, Verse 53


ثُمَّ إِذَا كَشَفَ ٱلضُّرَّ عَنكُمۡ إِذَا فَرِيقٞ مِّنكُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ

Leyin naa, nigba ti O ba si mu inira naa kuro fun yin tan, nigba naa ni apa kan ninu yin yo si maa sebo si Oluwa won
Surah An-Nahl, Verse 54


لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ

nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won. Nitori naa, e maa gbadun nso. Laipe e maa mo
Surah An-Nahl, Verse 55


وَيَجۡعَلُونَ لِمَا لَا يَعۡلَمُونَ نَصِيبٗا مِّمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡۗ تَٱللَّهِ لَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَفۡتَرُونَ

Won n fi ipin kan ninu ohun ti A pese fun won lele fun ohun ti won ko mo. Mo fi Allahu bura, dajudaju won yoo bi yin leere nipa ohun ti e n da ni adapa iro
Surah An-Nahl, Verse 56


وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ ٱلۡبَنَٰتِ سُبۡحَٰنَهُۥ وَلَهُم مَّا يَشۡتَهُونَ

Won tun n fi (bibi) awon omobinrin lele fun Allahu - Mimo ni fun Un (ko bimo). – Won si n fi ohun ti won n fe lele fun tiwon
Surah An-Nahl, Verse 57


وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِٱلۡأُنثَىٰ ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٞ

Nigba ti won ba fun okan ninu won ni iro idunnu (pe o bi) omobinrin, oju re yoo sokunkun, o si maa kun fun ibanuje
Surah An-Nahl, Verse 58


يَتَوَٰرَىٰ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ مِن سُوٓءِ مَا بُشِّرَ بِهِۦٓۚ أَيُمۡسِكُهُۥ عَلَىٰ هُونٍ أَمۡ يَدُسُّهُۥ فِي ٱلتُّرَابِۗ أَلَا سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ

O si maa fi ara pamo fun awon eniyan nitori iro aburu ti won fun un. Se o maa gba a ni nnkan abuku ni tabi o maa bo o mole laaye? E gbo, ohun ti won n da lejo buru
Surah An-Nahl, Verse 59


لِلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ مَثَلُ ٱلسَّوۡءِۖ وَلِلَّهِ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Ti awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ni akawe aburu. Ti Allahu si ni akawe t’o ga julo. Ati pe Oun ni Alagbara, Ologbon
Surah An-Nahl, Verse 60


وَلَوۡ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِظُلۡمِهِم مَّا تَرَكَ عَلَيۡهَا مِن دَآبَّةٖ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ لَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ سَاعَةٗ وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ

Ti o ba je pe Allahu n gba awon eniyan mu nitori abosi owo won, iba ti se abemi kan kan ku sori ile. Sugbon O n lo won lara di gbedeke akoko kan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di igba kan, won ko si nii fa a seyin.”
Surah An-Nahl, Verse 61


وَيَجۡعَلُونَ لِلَّهِ مَا يَكۡرَهُونَۚ وَتَصِفُ أَلۡسِنَتُهُمُ ٱلۡكَذِبَ أَنَّ لَهُمُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ لَا جَرَمَ أَنَّ لَهُمُ ٱلنَّارَ وَأَنَّهُم مُّفۡرَطُونَ

Won n fi (omobinrin) nnkan ti won korira lele fun Allahu. Ahon won si n royin iro pe dajudaju rere ni tawon. Ko si tabi-sugbon, dajudaju Ina ni tiwon. Ati pe dajudaju won maa pa won ti sinu re ni
Surah An-Nahl, Verse 62


تَٱللَّهِ لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَهُوَ وَلِيُّهُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Mo fi Allahu bura, dajudaju A ti ran awon Ojise nise si awon ijo kan siwaju re. Nigba naa, Esu se ise won ni oso fun won; oun si ni ore won lonii. Iya eleta-elero si wa fun won
Surah An-Nahl, Verse 63


وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا لِتُبَيِّنَ لَهُمُ ٱلَّذِي ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ

A ko so Tira naa kale fun o bi ko se pe ki o le salaye fun won ohun ti won n yapa enu si; o si je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo
Surah An-Nahl, Verse 64


وَٱللَّهُ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ

Allahu l’O n so omi kale lati sanmo. O si n fi ji ile leyin ti o ti ku. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo)
Surah An-Nahl, Verse 65


وَإِنَّ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَنۡعَٰمِ لَعِبۡرَةٗۖ نُّسۡقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِۦ مِنۢ بَيۡنِ فَرۡثٖ وَدَمٖ لَّبَنًا خَالِصٗا سَآئِغٗا لِّلشَّـٰرِبِينَ

Dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin, ti A n fun yin mu ninu nnkan t’o wa ninu re, (eyi) ti o n jade wa lati aarin boto inu agbedu ati eje. (O si n di) wara mimo t’o n lo tinrin ni ofun awon t’o n mu un
Surah An-Nahl, Verse 66


وَمِن ثَمَرَٰتِ ٱلنَّخِيلِ وَٱلۡأَعۡنَٰبِ تَتَّخِذُونَ مِنۡهُ سَكَرٗا وَرِزۡقًا حَسَنًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ

Ati pe lati ara awon eso dabinu ati eso ajara ni e ti n se oti ati ohun amu-soro t’o dara. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye
Surah An-Nahl, Verse 67


وَأَوۡحَىٰ رَبُّكَ إِلَى ٱلنَّحۡلِ أَنِ ٱتَّخِذِي مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتٗا وَمِنَ ٱلشَّجَرِ وَمِمَّا يَعۡرِشُونَ

Oluwa re si fi mo kokoro oyin pe: "Mu ile sinu apata, igi ati ohun ti (awon eniyan) mo ga
Surah An-Nahl, Verse 68


ثُمَّ كُلِي مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ فَٱسۡلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلٗاۚ يَخۡرُجُ مِنۢ بُطُونِهَا شَرَابٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ فِيهِ شِفَآءٞ لِّلنَّاسِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ

Leyin naa, je lara gbogbo eso, ki o si to awon oju ona Oluwa re pelu iteriba." Ohun mimu ti awo re yato sira won yoo maa jade lati inu kokoro oyin. Iwosan ni fun awon eniyan. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
Surah An-Nahl, Verse 69


وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ ثُمَّ يَتَوَفَّىٰكُمۡۚ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡ لَا يَعۡلَمَ بَعۡدَ عِلۡمٖ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٞ قَدِيرٞ

Allahu l’O seda yin. Leyin naa, O n gba emi yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da pada si ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alagbara
Surah An-Nahl, Verse 70


وَٱللَّهُ فَضَّلَ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلرِّزۡقِۚ فَمَا ٱلَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزۡقِهِمۡ عَلَىٰ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَهُمۡ فِيهِ سَوَآءٌۚ أَفَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ

Allahu l’O soore ajulo fun apa kan yin lori apa kan ninu arisiki. Awon ti A fun ni oore ajulo, ki won fun awon eru won ni arisiki won, ki won si jo pin in ni dogbadogba! Nitori naa, se idera Allahu ni won yoo maa tako
Surah An-Nahl, Verse 71


وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُم بَنِينَ وَحَفَدَةٗ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ أَفَبِٱلۡبَٰطِلِ يُؤۡمِنُونَ وَبِنِعۡمَتِ ٱللَّهِ هُمۡ يَكۡفُرُونَ

Ati pe Allahu se awon iyawo fun yin lati ara yin. O fun yin ni awon omo ati omoomo lati ara awon iyawo yin. O si pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Se iro (iyen, orisa) ni won yoo gbagbo, won yo si sai gbagbo ninu idera Allahu
Surah An-Nahl, Verse 72


وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَمۡلِكُ لَهُمۡ رِزۡقٗا مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ شَيۡـٔٗا وَلَا يَسۡتَطِيعُونَ

Dipo (ki won josin fun) Allahu, won n josin fun ohun ti ko ni ikapa arisiki kan kan fun won ninu sanmo ati ile; won ko si lagbara (lati se nnkan kan)
Surah An-Nahl, Verse 73


فَلَا تَضۡرِبُواْ لِلَّهِ ٱلۡأَمۡثَالَۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ

Nitori naa, e ma se fi awon akawe naa lele nipa Allahu. Dajudaju Allahu nimo; eyin ko si nimo
Surah An-Nahl, Verse 74


۞ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا عَبۡدٗا مَّمۡلُوكٗا لَّا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَمَن رَّزَقۡنَٰهُ مِنَّا رِزۡقًا حَسَنٗا فَهُوَ يُنفِقُ مِنۡهُ سِرّٗا وَجَهۡرًاۖ هَلۡ يَسۡتَوُۥنَۚ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

Allahu fi akawe kan lele (nipa) eru kan ti o wa labe oga, ti ko si le da nnkan kan se ati eni ti A fun ni arisiki t’o dara lati odo wa, ti o si n na ninu re ni ikoko ati ni gbangba. Se won dogba bi? Gbogbo ope n je ti Allahu. Sugbon opolopo won ni ko mo
Surah An-Nahl, Verse 75


وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا رَّجُلَيۡنِ أَحَدُهُمَآ أَبۡكَمُ لَا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَهُوَ كَلٌّ عَلَىٰ مَوۡلَىٰهُ أَيۡنَمَا يُوَجِّههُّ لَا يَأۡتِ بِخَيۡرٍ هَلۡ يَسۡتَوِي هُوَ وَمَن يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَهُوَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

Allahu tun fi akawe kan lele (nipa) okunrin meji kan, ti okan ninu won je odi, ti ko le da nnkan kan se, ti o tun je wahala fun oga re (nitori pe) ibikibi ti o ba ran an lo, ko nii mu oore kan bo (fun un lati ibe). Se o dogba pelu eni ti O n pase sise eto, ti o si wa loju ona taara
Surah An-Nahl, Verse 76


وَلِلَّهِ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَآ أَمۡرُ ٱلسَّاعَةِ إِلَّا كَلَمۡحِ ٱلۡبَصَرِ أَوۡ هُوَ أَقۡرَبُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ

Ti Allahu ni ikoko awon sanmo ati ile. Oro Akoko naa ko kuku tayo iseju tabi ki o tun sunmo julo. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
Surah An-Nahl, Verse 77


وَٱللَّهُ أَخۡرَجَكُم مِّنۢ بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ شَيۡـٔٗا وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفۡـِٔدَةَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ

Allahu l’O mu yin jade lati inu ikun awon iya yin nigba ti eyin ko ti i da nnkan kan mo. O si se igboro, awon iriran ati awon okan fun yin nitori ki e le dupe (fun Un)
Surah An-Nahl, Verse 78


أَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَى ٱلطَّيۡرِ مُسَخَّرَٰتٖ فِي جَوِّ ٱلسَّمَآءِ مَا يُمۡسِكُهُنَّ إِلَّا ٱللَّهُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ

Se won ko woye si awon eye ti A ro (fun fifo) ninu ofurufu (labe) sanmo? Ko si eni t’o n mu won duro (sinu ofurufu) bi ko se Allahu. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo
Surah An-Nahl, Verse 79


وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمۡ سَكَنٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ بُيُوتٗا تَسۡتَخِفُّونَهَا يَوۡمَ ظَعۡنِكُمۡ وَيَوۡمَ إِقَامَتِكُمۡ وَمِنۡ أَصۡوَافِهَا وَأَوۡبَارِهَا وَأَشۡعَارِهَآ أَثَٰثٗا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ

Allahu se ibusinmi fun yin sinu ile yin. Lati ara awo eran-osin, O tun se awon ile (atibaba) kan t’o fuye fun yin lati gbe rin ni ojo irin-ajo yin ati ni ojo ti e ba wa ninu ilu. Lati ara irun agutan, irun rakunmi ati irun ewure, e tun n ri awon nnkan oso ati nnkan igbadun lo titi fun igba die. aso eyi ti won ba fi irun agutan hun maa n je aso t’o roju julo ni rira. Nitori eyi aso irun agutan je aso awon mekunnu. Awon olowo ki i si fe ra a fun wiwo sorun nitori pe olufokansin eni esa onpero kookan ninu awon aafa onibidiah wonyen ba tun bere si fi oruko ara re pero dipo lilo oruko agbelero ti won dijo se adadaale re. Nigba naa ni aye won ba di ilana / toriko “at-tasowuffu al-kodiriyyah” ti okunrin kan ko ba ti ri ise halal se ni ise oojo o maa di “seeu”
Surah An-Nahl, Verse 80


وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَٰلٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡجِبَالِ أَكۡنَٰنٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ سَرَٰبِيلَ تَقِيكُمُ ٱلۡحَرَّ وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأۡسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُسۡلِمُونَ

Allahu se awon iboji fun yin lati ara nnkan ti O da. O se awon ibugbe fun yin lati ara awon apata. O tun se awon aso fun yin t’o n daabo bo yin lowo ooru ati awon aso t’o n daabo bo yin loju ogun yin. Bayen l’O se n pe idera Re le yin lori nitori ki e le je musulumi
Surah An-Nahl, Verse 81


فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ

Nitori naa, ti won ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse tire
Surah An-Nahl, Verse 82


يَعۡرِفُونَ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ

Won mo idera Allahu, leyin naa won n tako o. Opolopo won si ni alaimoore
Surah An-Nahl, Verse 83


وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ مِن كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدٗا ثُمَّ لَا يُؤۡذَنُ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ

(Ranti) ojo ti A oo gbe elerii kan dide ninu gbogbo ijo (awon Anabi), leyin naa, A o nii yonda (aroye sise) fun awon t’o sai gbagbo. Won ko si nii fun won ni aye lati pada se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu
Surah An-Nahl, Verse 84


وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلۡعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ

Nigba ti awon t’o sabosi ba ri Iya, nigba naa, A o nii se iya won ni fifuye, A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina)
Surah An-Nahl, Verse 85


وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ شُرَكَآءَهُمۡ قَالُواْ رَبَّنَا هَـٰٓؤُلَآءِ شُرَكَآؤُنَا ٱلَّذِينَ كُنَّا نَدۡعُواْ مِن دُونِكَۖ فَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلَ إِنَّكُمۡ لَكَٰذِبُونَ

Nigba ti awon t’o ba Allahu wa akegbe ba ri awon orisa won, won a wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ni awon orisa wa ti a n pe leyin Re.” Nigba naa (awon orisa) yoo ju oro naa pada si won pe: “Dajudaju opuro ma ni eyin.”
Surah An-Nahl, Verse 86


وَأَلۡقَوۡاْ إِلَى ٱللَّهِ يَوۡمَئِذٍ ٱلسَّلَمَۖ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ

Won si maa jura won sile fun Allahu ni ojo yen. Ohun ti won n da ni adapa iro yo si di ofo mo won lowo
Surah An-Nahl, Verse 87


ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ زِدۡنَٰهُمۡ عَذَابٗا فَوۡقَ ٱلۡعَذَابِ بِمَا كَانُواْ يُفۡسِدُونَ

Awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, A o se alekun iya lori iya fun won nitori pe won n sebaje
Surah An-Nahl, Verse 88


وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ فِي كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدًا عَلَيۡهِم مِّنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَجِئۡنَا بِكَ شَهِيدًا عَلَىٰ هَـٰٓؤُلَآءِۚ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ تِبۡيَٰنٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُسۡلِمِينَ

(Ranti) Ojo ti A oo gbe elerii dide fun ijo kookan laaarin ara won, A si maa mu iwo wa ni elerii fun awon wonyi. A so Tira kale fun o; (o je) alaye fun gbogbo nnkan, imona, ike ati iro idunnu fun awon musulumi
Surah An-Nahl, Verse 89


۞إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَٱلۡإِحۡسَٰنِ وَإِيتَآيِٕ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَيَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِ وَٱلۡبَغۡيِۚ يَعِظُكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ

Dajudaju Allahu n pase sise deede, sise rere ati fifun ebi (ni nnkan). O si n ko iwa ibaje, ohun buruku ati rukerudo. O n se waasi fun yin nitori ki e le lo iranti
Surah An-Nahl, Verse 90


وَأَوۡفُواْ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ إِذَا عَٰهَدتُّمۡ وَلَا تَنقُضُواْ ٱلۡأَيۡمَٰنَ بَعۡدَ تَوۡكِيدِهَا وَقَدۡ جَعَلۡتُمُ ٱللَّهَ عَلَيۡكُمۡ كَفِيلًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا تَفۡعَلُونَ

Ki e si mu adehun Allahu se nigba ti e ba se adehun. E ma se tu ibura leyin ifirinle re. E si kuku ti fi Allahu se Elerii lori ara yin. Dajudaju Allahu mo ohun ti e n se nise
Surah An-Nahl, Verse 91


وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّتِي نَقَضَتۡ غَزۡلَهَا مِنۢ بَعۡدِ قُوَّةٍ أَنكَٰثٗا تَتَّخِذُونَ أَيۡمَٰنَكُمۡ دَخَلَۢا بَيۡنَكُمۡ أَن تَكُونَ أُمَّةٌ هِيَ أَرۡبَىٰ مِنۡ أُمَّةٍۚ إِنَّمَا يَبۡلُوكُمُ ٱللَّهُ بِهِۦۚ وَلَيُبَيِّنَنَّ لَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ

Ki e si ma se da bi (obinrin) eyi ti o tu owu didi re pale leyin ti o ti di i le. Nse ni e n lo ibura yin fun etan laaarin ara yin nitori pe iran kan po ju iran kan lo. Dajudaju Allahu n dan yin wo pelu re ni. Ati pe ni Ojo Ajinde O kuku maa salaye fun yin ohun ti e n yapa enu si
Surah An-Nahl, Verse 92


وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَلَتُسۡـَٔلُنَّ عَمَّا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon O n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Dajudaju Won maa bi yin leere nipa ohun ti e n se nise
Surah An-Nahl, Verse 93


وَلَا تَتَّخِذُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡ دَخَلَۢا بَيۡنَكُمۡ فَتَزِلَّ قَدَمُۢ بَعۡدَ ثُبُوتِهَا وَتَذُوقُواْ ٱلسُّوٓءَ بِمَا صَدَدتُّمۡ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَكُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ

E ma se lo ibura yin fun etan laaarin ara yin, nitori ki ese yin ma baa ye gere leyin idurosinsin re, ati nitori ki e ma baa to iya buruku wo nipa bi e se seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Iya nla yo si wa fun yin
Surah An-Nahl, Verse 94


وَلَا تَشۡتَرُواْ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ ثَمَنٗا قَلِيلًاۚ إِنَّمَا عِندَ ٱللَّهِ هُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ

E ma se ta adehun Allahu ni owo pooku. Ohun ti n be lodo Allahu, o loore julo fun yin ti e ba mo
Surah An-Nahl, Verse 95


مَا عِندَكُمۡ يَنفَدُ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ بَاقٖۗ وَلَنَجۡزِيَنَّ ٱلَّذِينَ صَبَرُوٓاْ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Ohun t’o n be lodo yin maa tan. Ohun t’o n be lodo Allahu si maa wa titi laelae. Dajudaju A si maa fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san awon t’o se suuru lesan won
Surah An-Nahl, Verse 96


مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Enikeni ti o ba se ise rere, okunrin ni tabi obinrin, o si je onigbagbo ododo, dajudaju A oo je ki o lo igbesi aye t’o dara. Dajudaju A o si fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won
Surah An-Nahl, Verse 97


فَإِذَا قَرَأۡتَ ٱلۡقُرۡءَانَ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ ٱلرَّجِيمِ

Nigba ti o ba (fe) ke al-Ƙur’an, sa di Allahu nibi (aburu) Esu, eni eko
Surah An-Nahl, Verse 98


إِنَّهُۥ لَيۡسَ لَهُۥ سُلۡطَٰنٌ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ

Dajudaju ko si agbara kan fun un lori awon t’o gbagbo, ti won si n gbarale Oluwa won
Surah An-Nahl, Verse 99


إِنَّمَا سُلۡطَٰنُهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ يَتَوَلَّوۡنَهُۥ وَٱلَّذِينَ هُم بِهِۦ مُشۡرِكُونَ

Eni t’o lagbara lori re ni awon t’o n mu un ni ore ati awon t’o so o di akegbe Allahu
Surah An-Nahl, Verse 100


وَإِذَا بَدَّلۡنَآ ءَايَةٗ مَّكَانَ ءَايَةٖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يُنَزِّلُ قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مُفۡتَرِۭۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

Nigba ti A ba paaro ayah kan si aye ayah kan, Allahu l’O si nimo julo nipa ohun t’O n sokale, won a wi pe: “Iwo kan je aladapa iro ni.” Amo opolopo won ni ko nimo
Surah An-Nahl, Verse 101


قُلۡ نَزَّلَهُۥ رُوحُ ٱلۡقُدُسِ مِن رَّبِّكَ بِٱلۡحَقِّ لِيُثَبِّتَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُسۡلِمِينَ

So pe: “Emi mimo (molaika Jibril) l’o so o kale lati odo Oluwa re ni ti ododo nitori ki o le mu ese awon t’o gbagbo lododo rinle. (Ki o si le je) imona ati iro idunnu fun awon musulumi
Surah An-Nahl, Verse 102


وَلَقَدۡ نَعۡلَمُ أَنَّهُمۡ يَقُولُونَ إِنَّمَا يُعَلِّمُهُۥ بَشَرٞۗ لِّسَانُ ٱلَّذِي يُلۡحِدُونَ إِلَيۡهِ أَعۡجَمِيّٞ وَهَٰذَا لِسَانٌ عَرَبِيّٞ مُّبِينٌ

A si kuku ti mo pe dajudaju won n wi pe: “Sebi abara kan l’o n ko o (ni al-Ƙur’an).” Ede eni ti won n ye si (ti won n toka si pe o n ko o) ki i se elede Larubawa. Ede Larubawa ponnbele si ni (al-Ƙur’an) yii
Surah An-Nahl, Verse 103


إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَا يَهۡدِيهِمُ ٱللَّهُ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Dajudaju awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu, Allahu ko nii to won sona. Iya eleta-elero si wa fun won
Surah An-Nahl, Verse 104


إِنَّمَا يَفۡتَرِي ٱلۡكَذِبَ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ

Awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu l’o n da adapa iro (mo Allahu). Awon wonyen si ni opuro
Surah An-Nahl, Verse 105


مَن كَفَرَ بِٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ إِيمَٰنِهِۦٓ إِلَّا مَنۡ أُكۡرِهَ وَقَلۡبُهُۥ مُطۡمَئِنُّۢ بِٱلۡإِيمَٰنِ وَلَٰكِن مَّن شَرَحَ بِٱلۡكُفۡرِ صَدۡرٗا فَعَلَيۡهِمۡ غَضَبٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ

Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu leyin igbagbo re, yato si eni ti won je nipa, ti okan re si bale pelu igbagbo ododo, sugbon enikeni ti aigbagbo ba te lorun, ibinu lati odo Allahu n be lori won. Iya nla si wa fun won
Surah An-Nahl, Verse 106


ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا عَلَى ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Iyen nitori pe won feran isemi aye ju orun. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo
Surah An-Nahl, Verse 107


أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَسَمۡعِهِمۡ وَأَبۡصَٰرِهِمۡۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ

Awon wonyen ni awon ti Allahu ti fi edidi bo okan won, igboro won ati iriran won. Awon wonyen si ni afonufora
Surah An-Nahl, Verse 108


لَا جَرَمَ أَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ

Ko si tabi-sugbon, dajudaju awon ni olofo ni orun
Surah An-Nahl, Verse 109


ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ هَاجَرُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا فُتِنُواْ ثُمَّ جَٰهَدُواْ وَصَبَرُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ

Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o gbe ilu won ju sile leyin ti awon alaigbagbo ti ko ifooro ba won, leyin naa, ti won jagun esin, ti won si se suuru - dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun (fun won) leyin (ifooro ti won ri lodo awon alaigbagbo)
Surah An-Nahl, Verse 110


۞يَوۡمَ تَأۡتِي كُلُّ نَفۡسٖ تُجَٰدِلُ عَن نَّفۡسِهَا وَتُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ

(Ranti) Ojo ti emi kookan yoo de lati du ori ara re. A o si san emi kookan ni esan ohun ti o se nise; won ko si nii sabosi si won
Surah An-Nahl, Verse 111


وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا قَرۡيَةٗ كَانَتۡ ءَامِنَةٗ مُّطۡمَئِنَّةٗ يَأۡتِيهَا رِزۡقُهَا رَغَدٗا مِّن كُلِّ مَكَانٖ فَكَفَرَتۡ بِأَنۡعُمِ ٱللَّهِ فَأَذَٰقَهَا ٱللَّهُ لِبَاسَ ٱلۡجُوعِ وَٱلۡخَوۡفِ بِمَا كَانُواْ يَصۡنَعُونَ

Allahu fi akawe lele nipa ilu kan, ti o je (ilu) aabo ati ifayabale, ti arisiki re n te e lowo ni pupo ni gbogbo aye. Amo (won) se aimoore si awon idera Allahu. Nitori naa, Allahu fun won ni iya ebi ati ipaya to wo nitori ohun ti won n se nise
Surah An-Nahl, Verse 112


وَلَقَدۡ جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡهُمۡ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَهُمۡ ظَٰلِمُونَ

Ojise kuku ti de ba won laaarin ara won. Won si pe e ni opuro. Nitori naa, owo iya ba won. Alabosi si ni won
Surah An-Nahl, Verse 113


فَكُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلٗا طَيِّبٗا وَٱشۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ

E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin ni nnkan eto, t’o dara. Ki e si dupe oore Allahu ti o ba je pe Oun nikan soso ni e n josin fun
Surah An-Nahl, Verse 114


إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Ohun ti (Allahu) se ni eewo fun yin ni eran okunbete, eje, eran elede ati eyi ti won pa pelu oruko t’o yato si “Allahu”. Nitori naa, enikeni ti won ba fi inira ebi kan, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
Surah An-Nahl, Verse 115


وَلَا تَقُولُواْ لِمَا تَصِفُ أَلۡسِنَتُكُمُ ٱلۡكَذِبَ هَٰذَا حَلَٰلٞ وَهَٰذَا حَرَامٞ لِّتَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ

E ma se so nipa ohun ti ahon yin royin ni iro pe: “Eyi ni eto, eyi si ni eewo” nitori ki e le da adapa iro mo Allahu. Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere
Surah An-Nahl, Verse 116


مَتَٰعٞ قَلِيلٞ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Igbadun aye bin-intin (le wa fun won, amo) iya eleta-elero wa fun won (ni orun)
Surah An-Nahl, Verse 117


وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا مَا قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُۖ وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ

Ati pe A se ohun ti A so fun o siwaju ni eewo fun awon t’o di yehudi. A o si sabosi si won, sugbon awon ni won n sabosi si emi ara won
Surah An-Nahl, Verse 118


ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٌ

Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o se aburu pelu aimokan, leyin naa, ti won ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse leyin re dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, Asake-orun
Surah An-Nahl, Verse 119


إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ كَانَ أُمَّةٗ قَانِتٗا لِّلَّهِ حَنِيفٗا وَلَمۡ يَكُ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim je asiwaju-awokose-rere, olutele-ase Allahu, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si je ara awon osebo
Surah An-Nahl, Verse 120


شَاكِرٗا لِّأَنۡعُمِهِۚ ٱجۡتَبَىٰهُ وَهَدَىٰهُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

O maa n dupe awon idera Allahu. Allahu sa a lesa. O si to o si ona taara (’Islam)
Surah An-Nahl, Verse 121


وَءَاتَيۡنَٰهُ فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

A se ohun rere fun un nile aye. Ati pe ni orun dajudaju o maa wa ninu awon eni rere
Surah An-Nahl, Verse 122


ثُمَّ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ أَنِ ٱتَّبِعۡ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۖ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

Leyin naa, A fi imisi ranse si o pe ki o tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si wa lara awon osebo
Surah An-Nahl, Verse 123


إِنَّمَا جُعِلَ ٱلسَّبۡتُ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِۚ وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ

Awon ti won se (agbega) ojo Sabt fun ni awon t’o yapa enu nipa re. Dajudaju Oluwa re yoo kuku se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si
Surah An-Nahl, Verse 124


ٱدۡعُ إِلَىٰ سَبِيلِ رَبِّكَ بِٱلۡحِكۡمَةِ وَٱلۡمَوۡعِظَةِ ٱلۡحَسَنَةِۖ وَجَٰدِلۡهُم بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ

Pepe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an ati sunnah Anabi s.a.w.) ati waasi rere. Ki o si ja won niyan pelu eyi t’o dara julo. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni ti o sina kuro loju ona Re (’Islam). O si nimo julo nipa awon olumona (awon musulumi)
Surah An-Nahl, Verse 125


وَإِنۡ عَاقَبۡتُمۡ فَعَاقِبُواْ بِمِثۡلِ مَا عُوقِبۡتُم بِهِۦۖ وَلَئِن صَبَرۡتُمۡ لَهُوَ خَيۡرٞ لِّلصَّـٰبِرِينَ

Ti e (ba fe) gbesan (iya), e gbesan iru iya ti won fi je yin. Dajudaju ti e ba si se suuru, o ma si loore julo fun awon onisuuru
Surah An-Nahl, Verse 126


وَٱصۡبِرۡ وَمَا صَبۡرُكَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَلَا تَكُ فِي ضَيۡقٖ مِّمَّا يَمۡكُرُونَ

Se suuru. Iwo ko si le ri suuru se afi pelu (iranlowo) Allahu. Ma se banuje nitori won. Ma si se wa ninu ibanuje nitori ohun ti won n da ni ete
Surah An-Nahl, Verse 127


إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّٱلَّذِينَ هُم مُّحۡسِنُونَ

Dajudaju Allahu wa pelu awon t’o beru (Re) ati awon t’o n se rere
Surah An-Nahl, Verse 128


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 15
>> Surah 17

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai