Surah Al-Baqara Verse 105 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraمَّا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ وَلَا ٱلۡمُشۡرِكِينَ أَن يُنَزَّلَ عَلَيۡكُم مِّنۡ خَيۡرٖ مِّن رَّبِّكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَخۡتَصُّ بِرَحۡمَتِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn ọ̀ṣẹbọ kò fẹ́ kí wọ́n sọ oore kan kan kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Allāhu sì ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu sì ni Olóore ńlá