Surah Al-Baqara Verse 106 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqara۞مَا نَنسَخۡ مِنۡ ءَايَةٍ أَوۡ نُنسِهَا نَأۡتِ بِخَيۡرٖ مِّنۡهَآ أَوۡ مِثۡلِهَآۗ أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
A ò níí fi āyah kan pa āyah kan rẹ́ tàbí kí Á fi sílẹ̀ (bẹ́ẹ̀ ní ohun kíké nìkan), A máa mú èyí t’ó dára jù ú lọ tàbí irú rẹ̀ wá. Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan