Surah Al-Baqara Verse 177 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqara۞لَّيۡسَ ٱلۡبِرَّ أَن تُوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ قِبَلَ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ وَلَٰكِنَّ ٱلۡبِرَّ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ وَٱلۡكِتَٰبِ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ وَءَاتَى ٱلۡمَالَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ ذَوِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِ وَٱلسَّآئِلِينَ وَفِي ٱلرِّقَابِ وَأَقَامَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَى ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلۡمُوفُونَ بِعَهۡدِهِمۡ إِذَا عَٰهَدُواْۖ وَٱلصَّـٰبِرِينَ فِي ٱلۡبَأۡسَآءِ وَٱلضَّرَّآءِ وَحِينَ ٱلۡبَأۡسِۗ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُتَّقُونَ
Ki i se ohun rere ni ki e koju si agbegbe ibuyo oorun ati ibuwo oorun, amo (oluse) rere ni enikeni t’o ba gbagbo ninu Allahu, Ojo Ikeyin, awon molaika, Tira (al-Ƙur’an), ati awon Anabi. Tohun ti ife ti oluse-rere ni si owo, o tun n fi owo naa tore fun awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu, onirin-ajo (ti agara da), awon atoroje ati (itusile) l’oko eru. (Eni rere) yo maa kirun, yo si maa yo Zakah. (Eni rere ni) awon t’o n mu adehun won se nigba ti won ba se adehun ati awon onisuuru nigba airina-airilo, nigba ailera ati l’oju ogun esin. Awon wonyen ni awon t’o se (ise) ododo. Awon wonyen, awon si ni oluberu (Allahu)