Surah Al-Baqara Verse 178 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِصَاصُ فِي ٱلۡقَتۡلَىۖ ٱلۡحُرُّ بِٱلۡحُرِّ وَٱلۡعَبۡدُ بِٱلۡعَبۡدِ وَٱلۡأُنثَىٰ بِٱلۡأُنثَىٰۚ فَمَنۡ عُفِيَ لَهُۥ مِنۡ أَخِيهِ شَيۡءٞ فَٱتِّبَاعُۢ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَأَدَآءٌ إِلَيۡهِ بِإِحۡسَٰنٖۗ ذَٰلِكَ تَخۡفِيفٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَرَحۡمَةٞۗ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ بَعۡدَ ذَٰلِكَ فَلَهُۥ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se esan gbigba nibi ipaniyan ni oran- anyan fun yin. Olominira fun olominira, eru fun eru, obinrin fun obinrin. Enikeni ti won ba samoju kuro kini kan fun lati odo omo iya (eni ti won pa, ki eni ti o maa gba owo emi dipo emi) se ohun rere tele (owo ti o gba, ki eni ti o maa san’wo emi) san owo naa fun un ni ona t’o dara. Iyen ni igbefuye ati aanu lati odo Oluwa yin. Sugbon enikeni ti o ba tayo enu-ala (ofin) leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un