Surah Al-Baqara Verse 187 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraأُحِلَّ لَكُمۡ لَيۡلَةَ ٱلصِّيَامِ ٱلرَّفَثُ إِلَىٰ نِسَآئِكُمۡۚ هُنَّ لِبَاسٞ لَّكُمۡ وَأَنتُمۡ لِبَاسٞ لَّهُنَّۗ عَلِمَ ٱللَّهُ أَنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَخۡتَانُونَ أَنفُسَكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡ وَعَفَا عَنكُمۡۖ فَٱلۡـَٰٔنَ بَٰشِرُوهُنَّ وَٱبۡتَغُواْ مَا كَتَبَ ٱللَّهُ لَكُمۡۚ وَكُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ ٱلۡخَيۡطُ ٱلۡأَبۡيَضُ مِنَ ٱلۡخَيۡطِ ٱلۡأَسۡوَدِ مِنَ ٱلۡفَجۡرِۖ ثُمَّ أَتِمُّواْ ٱلصِّيَامَ إِلَى ٱلَّيۡلِۚ وَلَا تُبَٰشِرُوهُنَّ وَأَنتُمۡ عَٰكِفُونَ فِي ٱلۡمَسَٰجِدِۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَقۡرَبُوهَاۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ ءَايَٰتِهِۦ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ
Won se ale aawe ni eto fun yin lati sunmo awon iyawo yin; awon ni aso yin, eyin si ni aso won. Allahu mo pe dajudaju e n tan ara yin je (nipa aife sun oorun ife ni ale aawe). O ti gba ironupiwada yin, O si se amojukuro fun yin. Ni bayii, e sunmo won, ki e si wa ohun ti Allahu ko mo yin (ni omo). E je, e mu titi e o fi ri iyato laaarin owu funfun (iyen, imole owuro) ati owu dudu (iyen, okunkun oru) ni afemojumo. Leyin naa, e pari aawe naa si ale (nigba ti oorun ba wo). E ma se sunmo won nigba ti e ba n kora ro ninu awon mosalasi. Iwonyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale), e ma se sunmo on. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le beru (Re)