Surah Al-Baqara Verse 196 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَأَتِمُّواْ ٱلۡحَجَّ وَٱلۡعُمۡرَةَ لِلَّهِۚ فَإِنۡ أُحۡصِرۡتُمۡ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۖ وَلَا تَحۡلِقُواْ رُءُوسَكُمۡ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ ٱلۡهَدۡيُ مَحِلَّهُۥۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ بِهِۦٓ أَذٗى مِّن رَّأۡسِهِۦ فَفِدۡيَةٞ مِّن صِيَامٍ أَوۡ صَدَقَةٍ أَوۡ نُسُكٖۚ فَإِذَآ أَمِنتُمۡ فَمَن تَمَتَّعَ بِٱلۡعُمۡرَةِ إِلَى ٱلۡحَجِّ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۚ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖ فِي ٱلۡحَجِّ وَسَبۡعَةٍ إِذَا رَجَعۡتُمۡۗ تِلۡكَ عَشَرَةٞ كَامِلَةٞۗ ذَٰلِكَ لِمَن لَّمۡ يَكُنۡ أَهۡلُهُۥ حَاضِرِي ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
E se asepe ise Hajj ati ‘Umrah fun Allahu. Ti won ba si se yin mo oju ona, e fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eyin ko si gbodo fa irun ori yin titi di igba ti eran ore naa yo fi de aye re. Enikeni ninu yin ti o ba je alaisan tabi inira kan n be ni ori re, o maa fi aawe tabi saraa tabi eran pipa se itanran (fun kikanju fa irun ori). Nigba ti e ba fokanbale (ninu ewu), enikeni ti o ba se ‘Umrah ati Hajj ninu osu ise Hajj, o maa fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eni ti ko ba ri (eran ore), ki o gba aawe ojo meta ninu (ise) hajj, meje nigba ti e ba dari wale. Iyen ni (aawe) mewaa t’o pe. Iyen wa fun eni ti ko si ebi re ni Mosalasi Haram. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu le (nibi) iya