Surah Al-Baqara Verse 197 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي ٱلۡحَجِّۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيۡرَ ٱلزَّادِ ٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُونِ يَـٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Hajj sise (wa) ninu awon osu ti A ti mo. Nitori naa, enikeni ti o ba se e ni oran-anyan lori ara re lati se Hajj ninu awon osu naa, ko gbodo si oorun ife, ese dida ati ariyanjiyan ninu ise Hajj. Ohunkohun ti e ba se ni rere, Allahu mo on. E mu ese irin-ajo lowo. Dajudaju ese irin-ajo t’o loore julo ni isora (nibi ese elomiiran ati agbe sise l’asiko ise Hajj). E beru Mi, eyin onilaakaye