Surah Al-Baqara Verse 197 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي ٱلۡحَجِّۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيۡرَ ٱلزَّادِ ٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُونِ يَـٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí A ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ dídá àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò t’ó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè